Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 22, 2018
KAZAKHSTAN

À Ń Bẹ Àwọn Aláṣẹ ní Kazakhstan Pé Kí Wọ́n Dá Teymur Akhmedov Sílẹ̀

À Ń Bẹ Àwọn Aláṣẹ ní Kazakhstan Pé Kí Wọ́n Dá Teymur Akhmedov Sílẹ̀

Ọ̀rọ̀ Teymur Akhmedov ń ká tẹbí tọ̀rẹ́ lára gan-an. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov, ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta [61] ni, kó sì tó di pé wọ́n fi sí àtìmọ́lé láti ohun tó lé ní ọdún kan sẹ́yìn ni ìlera rẹ̀ ò ti dáa rárá. Ní February 8, 2018, wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún un kí wọ́n lè yọ kókó méjì tó wà nínú ara rẹ̀, àwọn dókítà sì rí i pé ọ̀kan nínú àwọn kókó yẹn fi hàn pé àrùn jẹjẹrẹ ti wà lára rẹ̀. Àwon ẹbí rẹ̀ àtàwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ ti bẹ àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n dá a sílẹ̀ látìmọ́lé tó wà, torí pé ọkàn wọn ò balẹ̀ lórí àhámọ́ tí wọ́n fi sí ní Pavlodar. Ibẹ̀ ò bójú mu fún un, wọ́n sì tún rí i pé ó ṣì nílò kó máa gbàtọ́jú nílé ìwòsàn. Àmọ́ ibi pẹlẹbẹ lọ̀bẹ ń fi lélẹ̀ ṣáá.

Àwọn ilé ẹjọ́ ní Kazakhstan ò tiẹ̀ ṣàánú Teymur Akhmedov rárá, ṣé ni wọ́n rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún, èyí tó máa pé lọ́dún 2022. Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ò ṣẹ̀, ṣe ló lo òmìnira ẹ̀sìn tó ní, torí ẹ̀ làwọn aláṣẹ ṣe mú un, tí wọ́n sì pè é lẹ́jọ́. Wọ́n tiẹ̀ tún ti fi orúkọ ẹ̀ sára àwọn tí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé àkáǹtì tí wọ́n ní ní báǹkì torí pé wọ́n fura sí i pé ó ń bá àwọn afẹ̀míṣòfò da nǹkan pọ̀. Ó ti pe ọ̀pọ̀ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, àmọ́ àwọn ilé ẹjọ́ ní Kazakhstan ti fagi lé gbogbo ẹ̀.

Àjọ UN Working Group on Arbitrary Detention tó ń rí sí títini mọ́lé láìnídìí sọ èrò wọn fún ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan, wọ́n rọ àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n dá Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sílẹ̀, kí wọ́n sì dá a láre ẹ̀sùn irọ́ tí wọ́n fi kàn án. Bákan náà, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ àṣẹ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè rọ ìjọba Kazakhstan pé kí wọ́n dá a sílẹ̀ kíákíá torí àìlera rẹ̀.

Agbẹjọ́rò Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sọ pé: “Ìwà ìrẹ́jẹ gbáà ni bí wọ́n ṣe fi Teymur sẹ́wọ̀n láìtọ́, tó tún wá jẹ́ pé ìlera rẹ̀ ò dáa, tó sì nílò ìtọ́jú. Bíi tàwọn àjọ tó ń bá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ṣiṣẹ́, àwa náà ń rọ àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan pé kí wọ́n ṣàánú, kí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní kíákíá.”