APRIL 18, 2018
KAZAKHSTAN
Wọ́n Dá Teymur Akhmedov Sílẹ̀ Torí Pé Ààrẹ Dárí Jì Í
Ní April 2, 2018, Ààrẹ Nursultan Nazarbayev ti Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan dárí ji Teymur Akhmedov tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61), tó sì ti lé lọ́dún kan báyìí tó ti wà lẹ́wọ̀n torí ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Àforíjì náà fọ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn mọ́ kúrò lọ́rùn rẹ̀. April 4 ni Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov mọ̀ pé wọ́n dárí ji òun, wọ́n sì dá a sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n bó tiẹ̀ jẹ́ pé nílé ìwòsàn ló wà, tára rẹ̀ ń kọ́fẹ pa dà lẹ́yìn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún un. Ó ti pa dà sílé báyìí, á sì túbọ̀ rọrùn fún un láti lọ máa gbàtọ́jú tó pọn dandan pé kó máa rí gbà torí àrùn jẹjẹrẹ tó ń bá a fínra.
Wọ́n Mú Un, Wọ́n Tì Í Mọ́lé, Wọ́n sì Fi Í Sẹ́wọ̀n Láìtọ́
Wọ́n mú Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n ní January 18, 2017 torí pé ó sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Ní oṣù bíi mélòó kan kí wọ́n tó mú un, ó jíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n ṣe bíi pé àwọn nífẹ̀ẹ́ sí ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́. Àṣé amí làwọn ọkùnrin náà jẹ́ fáwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ orílẹ̀-èdè Kazakhstan, ìyẹn Ìgbìmọ̀ Àwọn Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ (KNB), wọ́n sì ti dọ́gbọ́n gba ọ̀rọ̀ tí wọn jọ sọ pẹ̀lú rẹ̀ sílẹ̀. Ohùn tí wọ́n gbà sílẹ̀ yìí ni àwọn ọlọ́pàá KNB gùn lé tí wọ́n fi mú Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov, tí wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó “ń dá ìyapa ẹ̀sìn sílẹ̀,” ó sì ń polongo pé “ẹ̀sìn . . . òun ló dára jù,” èyí tó lòdì sí Abala kẹrìnléláàádọ́sàn-án (174), apá kejì nínú Òfin Ìwà Ọ̀daràn Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan.
Lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá ti mú Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov, wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, wọ́n sì tì í mọ́lé fún oṣù mẹ́ta kó tó di pé wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Ní May 2, 2017, ilé ẹjọ́ fi í sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún, wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta.
Agbẹjọ́rò Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov pe ọ̀pọ̀ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kí wọ́n lè dá a sílẹ̀, àmọ́ ilé ẹjọ́ ò fara mọ́ gbogbo ẹjọ́ tó pè. Lẹ́yìn tó ti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti fi ẹsẹ òfin tọ ọ̀rọ̀ náà lórílẹ̀-èdè Kazakhstan, ó ké gbé ọ̀rọ̀ lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ lágbàáyé pé kí wọ́n bá òun dá sí i. Ó fìwé tó ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣọwọ́ sí Ìgbìmọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó ń Rí sí Ìfinisẹ́wọ̀n Láìtọ́ (WGAD) àti Ìgbìmọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn.
Ní October 2017, ìgbìmọ̀ WGAD dá orílẹ̀-èdè Kazakhstan lẹ́bi pé wọ́n fi Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sẹ́wọ̀n, ó sì rọ ìjọba pé kó dá a sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀, torí pé ohun tí ọ̀gbẹ́ni náà ṣe “kò fa rúkèrúdò kankan kò sì kọjá ààlà òmìnira tó ní láti ṣe ẹ̀sìn rẹ̀.” Ní January 2018, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn rí ìwé ìbéèrè tí Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov kọ ní pàjáwìrì gbà, wọ́n sì sọ pé ní kíá, kí orílẹ̀-èdè Kazakhstan rí sí í pé ó rí ìtọ́jú ìṣègùn tó péye gbà. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn tún dábàá pé kí orílẹ̀-èdè Kazakhstan tún ronú lórí dídá a sílẹ̀ pátápátá, nígbà tí wọ́n bá fi máa ṣèpinnu tó kẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Wọ́n Dá A Sílẹ̀ Níkẹyìn
Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov wà lẹ́wọ̀n, àìsàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í peléke sí i. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, àwọn dókítà sọ fún pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ inú ìfun àti pé ṣe ni àrùn náà túbọ̀ ń burú sí i. Nítorí ìpinnu Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn pé kí wọ́n kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ lójú ẹsẹ̀ àti ohun míì táwọn ìgbìmọ̀ míì kárí ayé sọ, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan ní kí Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov kọ̀wé sí Ààrẹ Nazarbayev láti fi bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì.
Ó kọ̀wé láti bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì ní March 5, 2018, ó sì ní kí wọ́n bójú tó ìwé ẹ̀bẹ̀ náà láìjáfara torí pé òun gbọ́dọ̀ lọ gbàtọ́jú kíákíá kí àrùn jẹjẹrẹ tó ń ṣe òun yé ràn kiri ara òun. Kí èsì tó dé, àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n gbé Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov lọ sí Almaty, lórílẹ̀-èdè Kazakhstan, níbi tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ abẹ fún un ní March 27, 2018.
Ǹjẹ́ Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan Máa Túbọ̀ Fàyè Gba Òmìnira Ẹ̀sìn?
Inú Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov, ìyàwó rẹ̀, àtàwọn ọmọ wọn dùn pé wàhálà ọ̀rọ̀ ẹjọ́ náà ti dópin. Wọ́n tún dúpẹ́ pé Ààrẹ Nazarbayev fọ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kúrò lọ́rùn rẹ̀. Torí pé wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn án láìtọ́, ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé àkáǹtì rẹ̀ ní báńkì, èyí sì mú kí nǹkan nira gan-an fún ìyàwó rẹ̀ nígbà tó wà lẹ́wọ̀n.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé retí pé ìdáríjì tí Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov rí gbà yìí máa mú kí àwọn aláṣẹ lórílẹ̀-èdè Kazakhstan túbọ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí lómìnira láti máa ṣe ìsìn wọn láìsí ìdíwọ́.