Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JANUARY 27, 2015
KAZAKHSTAN

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣàfihàn Bíbélì Tuntun Lédè Kazakh ní Àpéjọ àti Nígbà Ètò Rírìn Yíká

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣàfihàn Bíbélì Tuntun Lédè Kazakh ní Àpéjọ àti Nígbà Ètò Rírìn Yíká

Gerrit Lösch tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Kazakh.

ALMATY, Kazakhstan—Ní àpéjọ agbègbè tá a ṣe ní September 26 sí 28, 2014, a mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Kazakh. Gbogbo ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọgọ́rùn méje àti mọ́kànlélógún [3,721] èèyàn tó pé jọ ló gba ẹ̀dà Bíbélì tuntun yìí.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Alexander Garkavets tó jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn èdè Turkic sọ nípa Bíbélì yìí pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ sí èdè Kazakh, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó túmọ̀ Bíbélì yìí ṣe iṣẹ́ ribiribi. Ó wúni lórí láti rí àwọn ọ̀nà tuntun tí wọ́n gbà túmọ̀ Bíbélì láti èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ sí èdè Kazakh. Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí wọ́n mú jáde bára mu pẹ̀lú èyí tá a ti ń lò tẹ́lẹ̀, èyí sì mú kó rọrùn fún gbogbo èèyàn láti lóye.”

Ètò rírìn yíká: Àwọn Ẹlẹ́rìí pa àwọn àgọ́ ayé àtijọ́ kí wọ́n lè pín ìpápánu níbẹ̀.

Ní October 3, ìyẹn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé àpéjọ náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kazakhstan pe tonílé tàlejò láti wá rìn yíká ọ́fíìsì wa, àwọn wọ̀nyí sì máa láǹfààní láti rí Bíbélì tuntun náà lédè Kazakh. Iléeṣẹ́ Radio Azattyq tó wà lórílẹ̀-èdè Kazakhstan sọ nípa ètò yìí, ó ní: “Àwọn aṣojú ìjọba láti ìlú Almaty ló wá síbẹ̀, ẹni tó ṣáájú wọn ni olórí Ẹ̀ka Tó Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Ìsìn, ìyẹn Nurzhan Zhaparkul. Àwọn míì tó wá ni àwọn aṣojú láti orílẹ̀-èdè míì, àwọn onímọ̀ nípa ìsìn àtàwọn míì.” Zhaparkul sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà wá tọwọ́ tẹsẹ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn nílùú Almaty. A mọrírì ohun tí wọ́n ṣe yìí torí pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ gan-an lẹ́nu iṣẹ́ wa.”

Olórí Ẹ̀ka Tó Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Ìsìn Nurzhan Zhaparkul (àárín), àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba míì láti Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Ìsìn nígbà tí wọ́n ń rìn yíká ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi ètò náà.

Ìwé ìkésíni tí wọ́n pín ní ìlú Almaty láti pe àwọn èèyàn wá síbi ètò rírìn yíká náà.

Polat Bekzhan tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Kazakhstan sọ pé: “Inú wa dùn láti rí báwọn èèyàn ṣe wá sí àpéjọ wa lọ́dún yìí, àti bí àwọn èèyàn lágbègbè yìí ṣe tẹ́wọ́ gba Bíbélì èdè Kazakh. Bákan náà, ètò tá a ṣe pé káwọn èèyàn rìn yíká ọ́fíìsì wa ṣàṣeyọrí torí pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn àtàwọn aládùúgbò wa ti túbọ̀ mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí i.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000

Kazakhstan: Polat Bekzhan, tẹlifóònù +7 727 232 36 62