MAY 17, 2017
KAZAKHSTAN
Àwọn Aláṣẹ ní Kazakhstan Fi Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Ń Ṣàìsàn Sẹ́wọ̀n, Wọ́n sì Fòfin Dè é Pé Kò Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn
ÌLÚ ALMATY, lórílẹ̀-èdè Kazakhstan—Ní May 2, 2017, ilé ẹjọ́ kan nílùú Astana, olú-ìlú orílẹ̀-èdè Kazakhstan, rán Teymur Akhmedov lọ sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún torí pé ó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìrọwọ́rọsẹ̀ ló ń ṣe é. Ilé ẹjọ́ sọ pé ó ń “dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn,” ó sì ń “gbé [ẹ̀sìn] kan ga ju àwọn yòókù lọ.” Yàtọ̀ sí pé wọ́n rán an lọ sẹ́wọ̀n, adájọ́ tún fòfin de Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov fún ọdún mẹ́ta pé kò gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta [61] ni Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov, ó ti níyàwó, ó sì ti bímọ mẹ́ta. Ṣe ni ilé ẹjọ́ ń fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu torí ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí torí pé, ó ní àrùn kan tó le gan-an, wọn ò sì jẹ́ kó gba ìtọ́jú tó yẹ. Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Ó sì ṣeé ṣe kí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn gbọ́ ẹjọ́ náà kí oṣù May tó parí tàbí kó jẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù June.
Ibi tí wọ́n bá ọ̀rọ̀ náà dé nìyẹn. January 18, 2017 lọ̀rọ̀ ọ̀hún ti ń rúgbó bọ̀. Lọ́jọ́ yẹn, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ààbò lórílẹ̀-èdè Kazakhstan mú Ọ̀gbẹ́ni Teymur Akhmedov, wọ́n sì lo Àpilẹ̀kọ 174(2) nínú Òfin tí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan ṣe lórí ìwà ọ̀daràn, tí ẹnu ò kò lórí ẹ̀, láti fẹ̀sùn kàn án. Wọ́n wá fi Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sí àtìmọ́lé fún oṣù mélòó kan kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, wọn ò sì jẹ́ kó gba ìtọ́jú tó yẹ. David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wọn, sọ pé: “Kárí ayé ni ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Teymur ti ká àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára. À ń retí pé àwọn aláṣẹ máa fagi lé àwọn ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí wọ́n fi kàn án yìí, wọ́n á sì dá Kristẹni olóòótọ́, tí kì í rúfin ìlú yìí sílẹ̀ kó lè pa dà sílé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀, kó sì lè gba ìtọ́jú pàjáwìrì tó nílò.”
Lójú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹ̀rí ni ohun tí ilé ẹjọ́ ìlú Astana ṣe yìí jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ní Kazakhstan ti ń ṣe bíi ti àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, tó ń ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí, pàápàá lórí bí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe fòfin de Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà. Ọ̀gbẹ́ni Semonian ṣàlàyé pé: “Bí ohun tí ìjọba ṣe lórí ẹ̀sìn wa ní Rọ́ṣíà, òfin tí ìjọba Kazakhstan sọ pé àwọn ṣe láti fi dènà àwọn agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n ń ṣì lò báyìí láti fẹ̀sùn kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tí wọ́n sì ṣe fún Teymur Akhmedov nìyẹn. Àwọn àjọ tó wà lábẹ́ ìjọba àpapọ̀, bí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè àti Àjọ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Tó Ń Rí sí Òmìnira Ẹ̀sìn Kárí Ayé, ti sọ fún àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan pé kí wọ́n má ṣi àwọn òfin yẹn lò mọ́ láti ṣèdíwọ́ fún ìjọsìn tá à ń ṣe ní ìrọwọ́rọsẹ̀.” Nígbà tó máa parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Kazakhstan ń jẹ wá lọ́kàn, à ń retí pé ìjọba ò ní fìyà jẹ wọ́n mọ́ torí pé wọ́n ń kọ́ àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bẹ́ẹ̀ àwọn èèyàn mọ̀ pé kárí ayé ni ẹ̀kọ́ yìí ti ń ṣèrànwọ́ láwùjọ. Gbogbo wa là ń retí ibi tí ẹjọ́ yìí máa já sí.”
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000
Kazakhstan: Bekzat Smagulov, +7-747-671-45-01