Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 6, 2018
KAZAKHSTAN

Teymur Akhmedov Lo 441 Ọjọ́ Lẹ́wọ̀n​—A Fọ̀rọ̀ Wá Òun àti Mafiza Ìyàwó Rẹ̀ Lẹ́nu Wò

Teymur Akhmedov Lo 441 Ọjọ́ Lẹ́wọ̀n​—A Fọ̀rọ̀ Wá Òun àti Mafiza Ìyàwó Rẹ̀ Lẹ́nu Wò

Lẹ́yìn tí Ààrẹ Nursultan Nazarbayev tó jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè Kazakhstan dá Arákùnrin Teymur Akhmedov sílẹ̀, wọ́n mú un kúrò látìmọ́lé ní April 4, 2018. Gbogbo ọjọ́ tó lò lẹ́wọ̀n jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mọ́kànlélógójì (441). Torí pé ó kàn ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn míì ni àwọn aláṣẹ ṣe mú un.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n dá Teymur sílẹ̀ lẹ́wọ̀n tí Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde (ìyẹn OPI) tó wà ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Warwick, ìpínlẹ̀ New York, bá òun àti Mafiza ìyàwó ẹ̀ sọ̀rọ̀. Àwọn méjèèjì ti pa dà báyìí sí ilé wọn nílùú Astana, tó jẹ́ olú ìlú Kazakhstan. Àwọn ohun tí wọ́n sọ la kọ sísàlẹ̀ yìí. A ti gé e kúrú, a sì kọ́ ọ lọ́nà tó máa jẹ́ kó ṣe kedere.

OPI: Arákùnrin Akhmedov, a máa kọ́kọ́ fẹ́ mọ̀ sí i nípa yín. Ìgbà wo lẹ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Teymur Akhmedov: October 9, 2005 ni mo ṣèrìbọmi. Kí n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, mi ò gbà pé Ọlọ́run wà. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mi ò fi gba Ọlọ́run gbọ́, mi ò sì ṣe ẹ̀sìn kankan. Nígbà tó yá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìyàwó mi lẹ́kọ̀ọ́, ó sì wù mí kí n mo ohun tí wọ́n jọ máa ń sọ. Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í dúró sẹ́yìn ilẹ̀kùn, kí n lè máa fetí kọ́ ohun tí wọ́n ń sọ.

Nígbà tí mo mọ ohun tí wọ́n ń kọ́ ọ, ó yà mí lẹ́nu torí pé kìkì àwọn nǹkan rere-rere ni wọ́n jọ ń sọ. Nígbà tó yá, àwọn Ẹlẹ́rìí fi mí mọ Arákùnrin Veslav tó wá láti Poland àmọ́ tó ń gbé ní Kazakhstan. Lọ́jọ́ tá a kọ́kọ́ jọ sọ̀rọ̀, mo sọ fún un pé: ‘Ìbéèrè kan ṣoṣo ni màá bi ẹ́. Tí ìdáhùn rẹ bá tẹ́ mi lọ́rùn, àá dọ̀rẹ́, àá sì jọ máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ. Àmọ́ tí mi ò bá gba ti ìdáhùn tó o fún mi, a ò ní lè jọ máa bọ́rọ̀ yìí lọ mọ́. O ò ní bínú sí mi, èmi náà ò sì ní bínú sí ẹ.’ Mo wá bi Arákùnrin Veslav léèrè ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú. Ó ṣí Bíbélì sí Oníwàásù 9:​5, ó sì sọ pé, ‘Tó o bá ka ẹsẹ Bíbélì yìí, wàá mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú.’ Nígbà tí mo kà á, mo rí i pé òtítọ́ nìyí. Torí náà mo gbà pé kó máa wá, kó sì máa kọ́ mi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bẹ́ ẹ ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, tẹ́ ẹ sì ṣèrìbọmi lọ́dún 2005.

Ẹ jẹ́ ká fi ìyókù lẹ̀ ná, ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ káwọn aláṣẹ tó mú yín. Ní May 2016, ẹ pàdé àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n láwọn nífẹ̀ẹ́ sí ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́. Láàárín oṣù mélòó kan, ẹ máa ń lọ bá wọn jíròrò látinú Bíbélì. Tẹ́ ẹ bá ronú pa dà sẹ́yìn sí àwọn ìgbà tẹ́ ẹ jọ máa ń jíròrò yẹn, ǹjẹ́ ẹ rántí ohunkóhun tí wọ́n sọ tàbí tí wọ́n ṣe tó mú ìfura lọ́wọ́?

TA: Bẹ́ẹ̀ ni, mo sọ fún wọn pé tá a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a sábà máa ń fẹ́ kó jẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan làá máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ dípò kó jẹ́ àwọn kan tó kóra jọ. Mo sọ pé á dáa kí kálukú wọn máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àmọ́ gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń sọ pé rárá, ìjíròrò aláwùjọ yẹn làwọn fẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀ẹ̀mélòó kan wà tí wọ́n pe àwọn míì wá síbi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n wá dara pọ̀ mọ́ wa, wọ́n á sì ní kí n tún ohun tá a jíròrò nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ gbẹ̀yìn sọ.

Mafiza Akhmedov: Ìgbà kan wà témi náà wà níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Mo kíyè sí i pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe díẹ̀ tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́. Mo tún kíyè sí i pé ilé tí wọ́n ń gbé gbówó lórí ju ilé tí ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń lè sanwó ẹ̀. Mo sọ fún wọn pé ìgbésí ayé olówó tí wọ́n ń gbé yàtọ̀ sí èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń gbé. Àmọ́ mo rí i pé ohun tí mo sọ bà wọ́n, ara wọn ò sì lélẹ̀. Nígbà tá à ń kúrò níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, ṣe ni wọ́n pe Teymur sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, èmi lọ dúró dè é níta, wọ́n sì sọ fún un pé kó má mú mi wá síbẹ̀ mọ́ nígbàkigbà tó bá fẹ́ wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́.

Ìgbà wo lẹ wá mọ̀ pé kì í ṣe pé àwọn ọkùnrin tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fẹ́ràn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pé àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Kazakhstan (ìyẹn KNB) ni wọ́n ń bá ṣiṣẹ́?

TA: Ìgbà tí ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀ ni mo tó mọ̀ pé àwọn ọlọ́pàá KNB ni wọ́n ń bá ṣiṣẹ́.

Báwo ló ṣe rí lára yín nígbà tí wọ́n mú yín, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn yín pé ẹ̀ ń “mú kí àwọn èèyàn kórìíra ẹ̀sìn míì” ẹ sì ń “gbé [ẹ̀sìn] kan ga ju ẹ̀sìn míì lọ”?

TA: Ká sòótọ́, nígbà tí wọ́n mú mi, ṣe ni mo rò pé bí wọ́n ṣe sọ, wọ́n máa mú mi lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá kí n lè ṣàlàyé tẹnu mi, kí wọ́n sì dá mi sílẹ̀. Mo ṣe tán láti gbèjà ara mi, kí n sì ṣàlàyé ohun tí mo bá àwọn ọkùnrin náà sọ.

Àmọ́ ohun tó wá ṣẹlẹ̀ yà mí lẹ́nu, síbẹ̀ mi ò bẹ̀rù. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí pé mò ń mú kí àwọn èèyàn kórìíra ẹ̀sìn míì, pé mo sì ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn yà mí lẹ́nu gan-an. Ọ̀rọ̀ nípa Jèhófà làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sọ, a ò sì fìgbà kankan ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìkórìíra tàbí ìyapa. Ó dá mi lójú hán-ún hán-ún pé mi ò mọwọ́ mẹsẹ̀, mo sì mọ̀ pé Jèhófà máa ràn mí lọ́wọ́. Òótọ́ ni pé ọkàn mi ò balẹ̀, àmọ́ mo rántí ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì, tó sọ pé, “ẹ . . . kó gbogbo àníyàn yín lé [Jèhófà], nítorí ó bìkítà fún yín.”​—1 Pétérù 5:7.

Nígbà tó di May 2, 2017, lẹ́yìn tẹ́ ẹ ti lo ohun tó lé ní oṣù mẹ́ta ní àtìmọ́lé, ilé ẹjọ́ kan nílùú Astana rán yín lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún, wọ́n sì tún fòfin dè yín pé ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ọdún mẹ́ta. Báwo ló ṣe rí lára yín?

TA: Nígbà tí ilé ẹjọ́ sọ bẹ́ẹ̀, mo gbà lọ́kàn ara mi pé tó bá pọn dandan, màá lo ọdún márùn-ún tí wọ́n dá fún mi pé. Ohun tí mo rò ni pé: ‘Tó bá jẹ́ pé àdánwò ló délẹ̀ yìí, Jèhófà ń rí gbogbo ẹ̀, ó mọ bó ṣe máa pẹ́ tó àtìgbà tó máa dópin.’ Torí náà, mo pinnu pé bó ti wù kó pẹ́ tó, màá dúró.

Ilé tí wọ́n ti ń tún ìwà ẹni ṣe nílùú Pavlodar ní Kazakhstan, ibẹ̀ ni Arákùnrin Akhmedov ti ṣẹ̀wọ̀n.

Àmọ́ nígbà tí wọ́n fi yín sẹ́wọ̀n yẹn, a mọ̀ pé ẹ̀ ń bá àìsàn kan tó le fínra. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

TA: Bẹ́ẹ̀ ni, ara mi ò yá, mo sì ń gbàtọ́jú kó tó di pé wọ́n rán mi lọ sẹ́wọ̀n. Àmọ́ nígbà tí wọ́n ti mú mi, wọ́n dá ìtọ́jú tí mò ń gbà dúró, àìsàn tó ń ṣe mí wá bẹ̀rẹ̀ sí í le sí i.

Arábìnrin Mafiza, báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára yín lásìkò yẹn?

MA: Ẹ̀rù bà mí gan-an, ìbànújẹ́ sì dorí mi kodò. Kódà, ó nira fún mi láti máa dá ìpinnu ṣe látìgbà tí wọ́n ti fi Teymur sẹ́wọ̀n, torí pé láti ọdún méjìdínlógójì (38) tá a ti ṣègbéyàwó, nǹkan kan ò yà wá rí. Àmọ́ Teymur sọ̀rọ̀ kan tó tù mí nínú, ó ní: ‘Fọkàn balẹ̀, ṣó o gbọ́? Ṣó o rí ọdún márùn-ún tá a máa fi pín yà yìí, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Jèhófà máa fi rọ́pò ẹ̀ fún wa kí Ìjọba Ọlọ́run tó dé!’

Kí lohun míì tó tún ràn yín lọ́wọ́ nígbà tí ọkọ yín wà lẹ́wọ̀n?

MA: Àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Nígbà tí wọ́n fi Teymur sẹ́wọ̀n, kí n má parọ́, ṣe ni mo rò pé ẹ̀rù á máa ba gbogbo wọn láti wá wò mí torí ohun tó fà á táwọn aláṣẹ fi mú Teymur. Kódà, àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ń ṣọ́ ilé wa, wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn nǹkan tá à ń ṣe.

Àmọ́ lọ́jọ́ kan, alàgbà kan àti ìyàwó ẹ̀ wá wò mí, ìṣírí ńlá gbáà ló jẹ́ fún mi. Mo bi wọ́n pé, ‘Ṣé ẹ̀rù ò bà yín láti wá síbí ni?’ Wọ́n dáhùn pé, ‘Kí ló fẹ́ máa bà wá lẹ́rù? Níbi táyé dé yìí, kò ṣòro rárá fáwọn aláṣẹ láti rí wa mú. Tí wọ́n bá fẹ́ mú wa, kò ju kí wọ́n fi kọ̀ǹpútà wá àdírẹ́sì ibi tá a ti ń pè lórí fóònù.’

Àwọn alàgbà wá ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì rọ̀ mí pé kí n má jẹ́ kí àdánwò tó délẹ̀ yìí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi, àmọ́ kí n jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi àti àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára.

Arákùnrin Teymur, kí ló ràn yín lọ́wọ́ tẹ́ ẹ fi fara da àdánwò yìí, tẹ́ ò sì sọ̀rètí nù?

Wọ́n de Arákùnrin Akhmedov mọ́ bẹ́ẹ̀dì nílé ìwòsàn ní Almaty kó tó di pé wọ́n tú u sílẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò kọ́kọ́ jẹ́ kó gbàtọ́jú, nígbà tí ìlera ẹ̀ di pé ó ń burú sí i, àwọn aláṣẹ gbà kí wọ́n tọ́jú rẹ̀.

TA: Àdúrà ni! Ojoojúmọ́ ni mo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ mi sọ́nà, kó fún mi lóye, kó sì jẹ́ kí n lókun kí n lè máa láyọ̀, kí n lè jẹ́ olóòótọ́, kí n má sì bọ́hùn lásìkò ìṣòro yìí. Mo sì rí bó ṣe dáhùn àdúrà mi. Kò fi mí sílẹ̀, torí mi ò mọ̀ ọ́n lára pé mo dá wà nínú ẹ̀wọ̀n.

Kíka Bíbélì náà ràn mí lọ́wọ́. Nínú ọ̀kan lára àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn, Bíbélì wà lárọ̀ọ́wọ́tó mi ní gbogbo ìgbà. Ní ọgbà ẹ̀wọ̀n míì tí wọ́n gbé mi lọ, wọ́n fi Bíbélì kan síbi ìkówèésí ní ọgbà náà, mo sì lè lọ máa kà á lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀.

Mo tún rántí ọ̀rọ̀ arákùnrin tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó máa ń sọ pé kò yẹ kí ìṣòro tá à ń kojú máa dẹ́rù bà wá. Mo rántí pé mo bi wọ́n pé: ‘Báwo ni mi ò ṣe ní bẹ̀rù? Tí ìṣòro yẹn bá le ńkọ́, tó sì ń dáyà já mi?’ Ó ní, Jèhófà ò ní jẹ́ ká dán wa wò kọjá ohun tá a lè mú mọ́ra, á sì fún wa lókun ká lè borí ìṣòro èyíkéyìí. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Torí náà, nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, mi ò gbàgbé ọ̀rọ̀ tí wọ́n fà yọ látinú Ìwé Mímọ́ yẹn.

Báwo ló ṣe rí lára yín nígbà tẹ́ ẹ gbọ́ pé gbogbo àwọn ará kárí ayé ló ti gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí yín, àti pé gbogbo wọn lọ́kùnrin lóbìnrin ló ń gbàdúrà fún yín?

TA: Ó dá mi lójú pé Jèhófà ló lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ yẹn torí pé òun náà ló ni ètò yìí. Ìyẹn fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn ará ò ní pa mí tì, àti pé lọ́jọ́ kan, Jèhófà máa kó mi yọ.

Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ohun tó bà mí lẹ́rù jù ni kí wọ́n fi mí sẹ́wọ̀n. Mo bẹ̀rù ọgbà ẹ̀wọ̀n gan-an. Tí mo bá ń ka ìtàn àwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n, ṣe ni mo máa ń gbàdúrà pé, ‘Jèhófà jọ̀ọ́, gbogbo nǹkan ni mo lè mú mọ́ra, àmọ́ bíi ti ẹ̀wọ̀n kọ́!’ Síbẹ̀, lẹ́sẹ̀ kan náà, ó máa ń wù mí gan-an láti lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wà lẹ́wọ̀n, kí n lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Mo béèrè nígbà kan bóyá a lè lọ máa wàásù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àmọ́ àwọn àrá ṣàlàyé pé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ìjọba ò fún wa láṣẹ láti máa lọ sáwọn ẹ̀wọ̀n tó wà ní Kazakhstan. Nígbà tó wá di pé nǹkan yí bìrí fún mi, bẹ́rù ṣe ń bà mí náà ni mo tún ń rò ó pé ohun tó máa ń wù mí láti ṣe, ìyẹn láti máa wàásù fáwọn ẹlẹ́wọ̀n, máa wá di ṣíṣe báyìí.

Ṣé àǹfààní ẹ̀ wá yọ láti wàásù fún àwọn kan nígbà tẹ́ ẹ wà lẹ́wọ̀n?

TA: Bẹ́ẹ̀ ni. Ìgbà kan wà tí agbófinró kan ránṣẹ́ sí mi pé òun fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo dé ọ́fíìsì ẹ̀, ó ní, ‘Mo ti mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, má lọ rò ó pé o fẹ́ wàásù fún mi!’ Mo fèsì pé, ‘Mi ò ní in lọ́kàn láti wàásù fún yín.’ Ó wá bi mí pé, ‘Kí lorúkọ Ọlọ́run?’ Mo ní, ‘Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run.’ Ó tún bi mí pé, ‘Ta wá ni Jésù? Ṣé òun kọ́ ni Ọlọ́run ni?’ Mo dáhùn pé, ‘Rárá, ọmọ Ọlọ́run ni.’ Ó wá béèrè pé, ‘Kí ló wá dé táwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì fi gbà pé òun ni Ọlọ́run?’ Mo ní, ‘Àwọn náà ni wọ́n máa lè dáhùn ẹ̀.’

Nǹkan míì tún ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan tó jẹ́ kí n lè bá àwọn tó tó ogójì (40) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Dókítà kan tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Ọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó là ń sọ lọ́jọ́ yẹn, ló bá bi wá pé kí lèrò wa nípa kéèyàn fẹ́yàwó púpọ̀. Gbogbo wa la láǹfààní láti sọ èrò wa.

Nígbà tí wọ́n ní kí n sọ èrò mi, mo sọ fún wọn pé èmi fúnra mi ò ní nǹkan kan sọ sí i, àmọ́ á wù mí kí n sọ ohun tẹ́nì kan rò nípa ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo wọn. Mo wá sọ pé: ‘Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin yóò ṣe fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Dókítà náà béèrè pé, ‘Èrò ta nìyẹn?’ Mo ní, ‘Èrò Jèhófà Ọlọ́run ni, ẹni tó dá ọmọ aráyé. Èèyàn méjì ló sọ pé wọ́n á ṣègbéyàwó; wọn ò ju méjì lọ.’

Dókítà náà wá bi mí pé, ‘Ṣé ìdí míì wà tó o fi rò pé ìyàwó kan ṣoṣo ló yẹ kí ọkùnrin ní?’ Mo fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Mátíù 7:​12, tó sọ pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” Mo ní: ‘Jésù ló sọ̀rọ̀ yìí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ bi àwọn ọkùnrin tó jókòó síbí bóyá ó máa wù wọ́n kí àwọn àti ọkùnrin míì jọ máa fẹ́ ìyàwó wọn. Tó bá jẹ́ pé àwọn ọkùnrin ò fẹ́ kí ìyàwó àwọn ní ọkọ míì, nígbà náà, ó dájú pé àwọn ìyàwó náà ò ní fẹ́ kí ọkọ àwọn níyàwó míì.’ Dókítà náà sọ pé nínú ọ̀rọ̀ tí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ sọ, ọ̀rọ̀ tèmi lòun gbádùn jù.

Ìṣírí ló jẹ́ fún wa pé láìka bí nǹkan ṣe nira fún yín tó, ẹ ṣì wá àǹfààní láti wàásù fún àwọn tó wà nítòsí yín!

Lẹ́yìn táwọn ilé ẹjọ́ kọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà láti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n dá yín sílẹ̀, tó fi mọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Kazakhstan pàápàá, ṣe ló dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ mọ́ lábẹ́ òfin.

Síbẹ̀, wọ́n fún yín láǹfààní láti buwọ́ lùwé kan tẹ́ ẹ bá fẹ́ kí wọ́n dá yín sílẹ̀. Ṣé ẹ lè sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa àti ìdí tẹ́ ẹ fi kọ̀ láti buwọ́ lù ú?

TA: Òótọ́ ni pé àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n ní kí n buwọ́ lùwé. Ó jọ bíi pé ìrànlọ́wọ́ ni wọ́n fẹ́ ṣe fún mi, àmọ́ ohun tó wà nínú ìwé yẹn ni pé mo jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí àti pé mo tọrọ àforíjì fún ohun tí mo ṣe. Nígbà tó yá, wọ́n ní kí n kọ̀wé míì fúnra mi láti jẹ́wọ́ ohun tí mo ṣe, kí n sì bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n tú mi sílẹ̀. Ohun táwọn aláṣẹ ní kí n kọ ni pé àṣìṣe ni mo ṣe bí mo ṣe bá àwọn míì sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo gbà gbọ́, àmọ́ pé ní báyìí, mo tọrọ àforíjì fún ohun tí mo ṣe, mo sì ń bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n tú mi sílẹ̀ torí àìlera mi.

Mo kọ̀ láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn, mo sì sọ fáwọn aláṣẹ pé ó pé mi kí n wà lẹ́wọ̀n pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ju kí wọ́n tú mi sílẹ̀ àmọ́ kí ẹ̀rí ọkàn mi máa dá mi lẹ́bi.

A mọyì àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tẹ́ ẹ ní gan-an àti bẹ́ ẹ ṣe kọ̀ láti ṣe ohun tó máa ba ẹ̀rí ọkàn yín jẹ́.

Nígbà tó yá, ohun tá ò retí ṣẹlẹ̀. Ṣé ẹ lè sọ fún wa nípa bẹ́ ẹ ṣe mọ̀ pé ìjọba fẹ́ tú yín sílẹ̀ lẹ́wọ̀n?

TA: Lọ́jọ́ kan, ẹ̀ṣọ́ kan wá sí yàrá mi, ó sọ fún mi pé ẹnì kan fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Mo rò ó pé, ‘Ta ló lè fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀?’ Nígbà tí mo gbé fóònù, obìnrin lẹni náà, ó sọ bóun ṣe jẹ́ fún mi, ó sì sọ pé òun ń bọ̀ wá tú mi sílẹ̀. Kí n má parọ́, mi ò mọ ohun tí mi ò bá ṣe. Nígbà tá a sọ̀rọ̀ tán lórí fóònù, mo pinnu pé màá sọ fún ọmọ mi ọkùnrin, mi ò fẹ́ sọ fún ìyàwó mi torí kí n má bàa kó o lọ́kàn sókè, a ò sì mọ̀ bóyá wọ́n á tú mi sílẹ̀ lóòótọ́, kí n má lọ fojú ẹ̀ sọ́nà.

Bí mo ṣe gbé fóònù náà kalẹ̀, ẹ̀ṣọ́ yẹn bi mí pé, ‘Kí ni wọ́n sọ fún ẹ lórí fóònù?’ Mo ní ẹnì kan ló ń bá mi dá àpárá jàre, torí ṣe ni obìnrin tí mo bá sọ̀rọ̀ kàn sọ pé òun ń bọ̀ wá tú mi sílẹ̀.

Mark Sanderson, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, pẹ̀lú Teymur àti Mafiza Akhmedov lẹ́yìn tí wọ́n dá Arákùnrin Akhmedov sílẹ̀.

Ẹ̀ṣọ́ yẹn sọ fún mi pé kì í ṣọ̀rọ̀ eré o, òótọ́ lobìnrin yẹn ń sọ o.

Arábìnrin Mafiza, báwo ni ìròyìn amóríyá yìí ṣe rí lára yín?

MA: Nígbà tí ọmọ mi sọ fún mi, èmi náà rò pé ó ń ṣeré ni. Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń retí irú ìròyìn bẹ́ẹ̀!

Àwa ò lè mọ bínú ẹ̀yin méjèèjì ṣe máa dùn tó nígbà tí Arákùnrin Teymur pa dà sílé lẹ́yìn ohun tó lé ní ọdún kan táwọn aláṣẹ ti mú wọn lọ!

Tẹ́ ẹ bá ronú pa dà sẹ́yìn nípa àdánwò ìgbàgbọ́ tẹ́ ẹ kojú yìí, ẹ̀kọ́ wo lẹ lè sọ pé ẹ kọ́?

MA: Mo rántí bí ọ̀rọ̀ Arákùnrin Bahram [Hemdemov] àti [Arábìnrin] Gulzira Hemdemov ṣe máa ń pa mí lẹ́kún tó. [Àwọn aláṣẹ ní Turkmenistan mú Arákùnrin Hemdemov ní March 2015. Nígbà tó di May 19, 2015, wọ́n rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin lórí ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án pé ó ń “mú kí àwọn èèyàn kórìíra ẹ̀sìn míì”, wọn ò sì tíì tú u sílẹ̀ lẹ́wọ̀n di báyìí.] Kódà, kí wọ́n tó mú Teymur, mo ronú nípa bó ṣe máa nira tó fún Gulzira. Ní báyìí, á wù mí báyìí kí n rí i, kí n gbá a mọ́ra, kí n sì jẹ́ kó mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, mo sì wà lẹ́yìn ẹ̀. Torí ohun tí ojú èmi àti Teymur ti rí yìí, á wù mí kí n sọ fún Gulzira pé mo bá a kẹ́dùn torí ohun tójú tiẹ̀ náà rí. Mo mọ̀ pé bíi tèmi, Jèhófà àtàwọn ará lòun náà gbára lé.

Ọpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ará tó tì wá lẹ́yìn, látorí àwọn ará ìjọ wa àti gbogbo ìjọ kárí ayé, tó fi mọ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí, àwọn agbẹjọ́rò àtàwọn ọmọkùnrin wa.

Arákùnrin Akhmedov di ìwé ẹ̀rí tí wọ́n fi dá a sílẹ̀ mú lẹ́yìn tó kúrò lẹ́wọ̀n.

TA: Ohun kan tí mo fẹ́ sọ ni pé gbogbo wa la máa kojú àdánwò. Ó lè má jẹ́ gbogbo wa la máa lọ sẹ́wọ̀n. Àdánwò táwọn míì máa kojú lè jẹ́ inúnibíni látọ̀dọ̀ mọ̀lẹ́bí wọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ní tàwọn míì, ó lè jẹ́ arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú ìjọ tó ṣòroó bá lò. Ìṣòro tàbí àdánwò yòówù ká máa kojú, gbogbo wa la máa pinnu ohun tá a máa ṣe, bóyá ìlànà Ọlọ́run la fẹ́ rọ̀ mọ́ àbí ìdàkejì ẹ̀ la fẹ́ ṣe. Tá a bá rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà yẹn, a máa lè borí àdánwò. Ohun tó dáa jù tá a le ṣe tá a bá ń kojú àdánwò ni pé, ká gbà pé àdánwò ló délẹ̀ yìí, ká sì máa rántí pé Jèhófà máa fún wa lókun ti àá fi borí ẹ̀.

Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ ìdílé mi àtàwọn ọmọ mi, wọ́n kú àdúrótì. Gbogbo àǹfààní tó bá yọ ni wọ́n fi ń wá wò mí, ìyẹn ò sì jẹ́ kí n rẹ̀wẹ̀sì.

Bákan náà, mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ará fún gbogbo ohun tí wọ́n ṣe. Mo mọrírì àdúrà wọn àtàwọn lẹ́tà tó ń gbéni ró tí wọ́n kọ sí mi. Mi ò mọ̀ ọ́n lára pé wọ́n pa mí tì fún ìṣẹ́jú kan. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti jẹ́ kí ìfẹ́ tí mo ní sí ẹgbẹ́ ará pọ̀ sí i, ó sì ti jẹ́ kí àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i.