Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JANUARY 17, 2018
KAZAKHSTAN

Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè Rọ Àwọn Aláṣẹ Kazakhstan Pé Kí Wọ́n Wá Nǹkan Ṣe sí Ọ̀rọ̀ Teymur Akhmedov

Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè Rọ Àwọn Aláṣẹ Kazakhstan Pé Kí Wọ́n Wá Nǹkan Ṣe sí Ọ̀rọ̀ Teymur Akhmedov

Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ti gbé ìgbésẹ̀ kánmọ́kánmọ́ lórí ìwé kan tí àwọn agbẹjọ́rò kọ ní January 3, 2018, lórúkọ Teymur Akhmedov. Ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61) ni Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov, ìlera rẹ̀ ò sì dáa. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan tó ti wà látìmọ́lé. Níwọ̀n ìgbà tó ti jẹ́ pé àwọn ilé ẹjọ́ ní Kazakhstan ò gba ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó pè wọlé, tí wọ́n sì sọ pó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó ń ṣèjọsìn tí kò bófin mu, torí ẹ̀ ni Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ṣe yíjú sí Ìgbìmọ̀ yìí pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́.

Nínú ìwé kan tí Ìgbìmọ̀ náà kọ ní January 9, 2018 láti fèsì, wọ́n rọ àwọn aláṣẹ Kazakhstan pé kí wọ́n kọ́kọ́ bójú tó ìlera Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ná, kó tiẹ̀ tó di pé àwọn máa ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀. Wọ́n rọ àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n “má jáfara, kí wọ́n rí i pé [Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov] rí ìtọ́jú tó péye gbà, kí wọ́n sì rí i pé ohun tí wọ́n ń ṣe fún un látìmọ́lé bá ohun tó wà nínú [ìwé International Covenant on Civil and Political Rights] àtàwọn ìlànà ìjọba àpapọ̀ kárí ayé mu.” Bákan náà, wọ́n sọ fáwọn aláṣẹ pé kí wọ́n “ronú àtidá [a] sílẹ̀ látìmọ́lé torí ìlera ẹ̀, tàbí kí wọ́n jẹ́ kó wà nínú ilé láìní jáde títí Ìgbìmọ̀ náà á fi bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀.”

Ohun tí Ìgbìmọ̀ yẹn sọ pé káwọn aláṣẹ kọ́kọ́ bójú tó ìlera Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov fi hàn pé ọ̀rọ̀ ìlera rẹ̀ ká àwọn náà lára, ó ṣe tán, Àjọ Tó Ń Rí sí Títini Mọ́lé Láìnídìí lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè náà sọ bẹ́ẹ̀. Ní October 2017, Àjọ yẹn ṣàyẹ̀wò ìwé tí Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov kọ sí wọn, wọ́n sì rí i pé kò sídìí fún un láti wà látìmọ́lé àti pé ó yẹ káwọn aláṣẹ dá a sílẹ̀, kí wọ́n sì sanwó gbà-máà-bínú fún un torí ìyà tí wọ́n fi jẹ́ ẹ́ lọ́nà àìtọ́. Àmọ́ títí di báyìí, ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan ò ṣàtúnṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó tí Àjọ náà sọ pé wọ́n ṣe. Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lo ọdún kan nínú ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún tí dá fún un.