Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 21, 2017
KAZAKHSTAN

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Kazakhstan Fagi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Tí Teymur Akhmedov Pè

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Kazakhstan Fagi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Tí Teymur Akhmedov Pè

Ní December 4, 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Kazakhstan fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Ọ̀gbẹ́ni Teymur Akhmedov pè lórí bí wọ́n ṣe dá a lẹ́bi láìtọ́ pé ó ń ṣe ìjọsìn tí kò bófin mu. Ká sòótọ́, ṣe ló kàn ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn míì. Àtìgbà tí wọ́n ti mú Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ní January 18, 2017 ni wọ́n ti fi sí àtìmọ́lé, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ló fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n dẹkùn mú un. Ilé ẹjọ́ kan dá a lẹ́bi lóṣù May, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún. Nígbà tó sì pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, ilé ẹjọ́ fagi lé e ní June 20, 2017, wọ́n ní dandan, kó fẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún gbára.

Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ń ṣàyẹ̀wò ẹjọ́ ọ̀gbẹ́ni yìí, wọn ò kọbi ara sí ìpinnu tí àjọ UN Working Group on Arbitrary Detention ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyẹn Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìtinimọ́lé Láìnídìí lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè. Àjọ yìí sọ pé ìjọba Kazakhstan jẹ̀bi bí wọ́n ṣe fi Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov sí àtìmọ́lé láìnídìí, tí wọ́n sì fi òmìnira ẹ̀sìn tó ní dù ú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìlera Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov ò dáa rárá, ó ṣì nígbàgbọ́ tó lágbara àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run. Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov mọrírì àwọn tó sapá kí ilé ẹjọ́ lè tètè dá a sílẹ̀, àmọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi pẹlẹbẹ lọ̀bẹ ń fi lélẹ̀ ṣáá, ó ṣì ń dúpẹ́ pé àwọn ará òun kárí ayé ò dákẹ́ àdúrà pé kí àwọn aláṣẹ tún òun sílẹ̀.