JULY 6, 2017
KAZAKHSTAN
Ìjọba Ní Kí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-èdè Kazakhstan Dáwọ́ Iṣẹ́ Dúró
Ní June 29, 2017, ilé ẹjọ́ kan nílùú Almaty lórílẹ̀-èdè Kazakhstan bu owó ìtanràn lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kazakhstan, wọ́n sì ní kí wọ́n dáwọ́ gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ dúró fún oṣù mẹ́ta. Ohun tó mú kí ilé ẹjọ́ ṣèpinnu yìí ni àyẹ̀wò kan táwọn aláṣẹ lọ ṣe sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Wọ́n sọ pé ó yẹ kí wọ́n ṣì ní kámẹ́rà mẹ́ta sí i yàtọ̀ sí kámẹ́rà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀, tó ń gbé ohun tó ń lọ láyìíká. Wọ́n ní ìyẹn ló bá òfin tí ìjọba ṣe mu lórí ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ kí àwọn ibi tí èrò púpọ̀ máa ń lọ rí. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ní February 6, 2017, àwọn aláṣẹ rí àwòrán bí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà ṣe rí, pẹ̀lú gbogbo ibi tí wọ́n fi kámẹ́rà sí níbẹ̀, wọ́n sì ti fọwọ́ sí i. Níwọ̀n ìgbà táwọn aláṣẹ ti fọwọ́ sí i, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé ohun táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà bá òfin tí ìjọba ṣe mu.
Polat Bekzhan, tó jẹ́ alága Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà, sọ pé: “Ìyà tí wọ́n fi ń jẹ wá yìí, ìyẹn bí wọ́n ṣe ní kí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wa dáwọ́ iṣẹ́ dúró, ti pọ̀ ju ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá lọ. A máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, torí ó jọ pé ẹ̀tanú ẹ̀sìn ló mú kí wọ́n ṣohun tí wọ́n ṣe yìí.”
Àwọn Aláṣẹ Ń Ṣèdíwọ́ fún Iṣẹ́ tí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Náà Ń Ṣe
Àwọn agbófinró lórílẹ̀-èdè Kazakhstan ń fi ojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí màbo, kódà wọn ò mú un ní kékeré rárá. Kí Adájọ́ N. M. Pakirdinov, tó wá láti ilé ẹjọ́ Specialized Interdistrict Administrative Court, tó dájọ́ ní June 29, àwọn aláṣẹ ya lọ sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà ní May 17, wọ́n láwọn fẹ́ ṣàyẹ̀wò ààbò ibẹ̀. Ojúmọmọ ni wọ́n wá síbẹ̀. Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba (tí wọ́n ń pè ní ọlọ́pàá KGB tẹ́lẹ̀) ló wá ṣe àyẹ̀wò ọ̀hún, wọ́n kó ọlọ́pàá tó lé ní ọgbọ̀n [30] dání, títí kan àwọn ọlọ́pàá SWAT tí wọn bo ojú, tí wọ́n sì gbé ẹ̀rọ arọ̀jò ọta wá. Wọ́n sọ pé ìjọba ló fún àwọn láṣẹ láti máa yẹ àwọn ibi tí èrò púpọ̀ máa ń lọ wò kó tó dìgbà ìpàtẹ tó máa wáyé lọ́dún 2017, kí ẹ̀mí àwọn èèyàn má bàa sí nínú ewu. June 2017 ni ìpàtẹ náà bẹ̀rẹ̀ nílùú Astana, tó jẹ́ olú ìlú Kazakhstan.
Ní June 23-25, 2017, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe àkànṣe ìpàdé àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta. Àwọn àlejò wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ilẹ̀ Yúróòpù, orílẹ̀-èdè Ukraine, Jọ́jíà, Kyrgyzstan àtàwọn orílẹ̀-èdè míì. Kó tó dìgbà àpéjọ àgbègbè náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti gba ibi tí wọ́n máa lò, àmọ́ ṣe làwọn aláṣẹ lọ da ìṣètò wọn rú, bó ṣe di pé wọn ò ríbi tí wọ́n á ti ṣe àpéjọ náà nìyẹn. Inú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà ni wọ́n ti wá pa dà ṣe é, ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] àwọn aṣojú ló kóra jọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tó wà nílùú yẹn.
Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe àpéjọ náà, bọ́ọ̀sì mọ́kànlá [11] tí nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì kún inú rẹ̀ làwọn ọlọ́pàá dá dúró ní òtẹ́ẹ̀lì ibi tí wọ́n dé sí. Wákàtí méjì ni wọ́n fi dá wọn dúró, wọ́n láwọn fẹ́ wò ó bóyá ìwé àwọn awakọ̀ pé. Nígbà tó tún di ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, ogún [20] bọ́ọ̀sì tí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì kún nínú rẹ̀ làwọn ọlọ́pàá tún dá dúró ní òtẹ́ẹ̀lì ibi tí wọ́n dé sí. Lọ́tẹ̀ yìí, wákàtí mẹ́ta ni wọ́n fi dá wọn dúró, wọ́n láwọn tún fẹ́ wò ó bóyá ìwé àwọn awakọ̀ pé.
Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà kọ̀wé sí Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò nílùú Almaty láti fẹjọ́ sùn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fún àwọn Ẹlẹ́rìí lésì, àwọn ọlọ́pàá ò yọ wọ́n lẹ́nu ní ọjọ́ kẹta àpéjọ àgbègbè náà. Àmọ́ kò ju ọjọ́ mẹ́rin tí wọ́n ṣe àpéjọ àgbègbè náà tí ilé ẹjọ́ ìlú Almaty fi sọ pé kí Ẹ̀ka ọ́fíìsì náà dáwọ́ iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe dúró.
Wọ́n Ń Fi Òfin Dáná Wàhálà
Láti December 2012, ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan ti túbọ̀ ń fúngun mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà, wọn ò jẹ́ kí wọ́n lómìnira ẹ̀sìn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọgọ́ta [60] ni ìjọba ti bu owó ìtanràn gọbọi lé, wọ́n sọ pé wọ́n ń “ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì” láì forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin.
Ní January 2017, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́jọ́ lẹ́ẹ̀mejì, wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n torí pé wọ́n ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Nígbà tó di May, ilé ẹjọ́ dá Teymur Akhmedov lẹ́bi torí pé ó ń ṣe ẹ̀sìn rẹ̀, ó ń ṣẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún lọ́wọ́ báyìí. Yàtọ̀ sí ẹjọ́ Ọ̀gbẹ́ni Akhmedov, àwọn ọlọ́pàá ń ṣèwádìí lórí ọ̀rọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan, wọ́n sọ pé ó ń mú káwọn èèyàn kórìíra àwọn ẹ̀sìn míì torí pé ó fún wọn ní ìwé ẹ̀sìn tí àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti fòfin dè pé ó jẹ́ ti àwọn “agbawèrèmẹ́sìn.”
Ṣé Ohun tí Ìjọba Ń Ṣe fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà ni Ìjọba Orílẹ̀-èdè Kazakhstan Náà Máa Ṣe?
Léraléra ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn kí wọ́n lè jọ sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti jọ́sìn, àmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ sèso rere. Ṣùgbọ́n Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà gbé ìgbésẹ̀ kan, wọ́n mú kí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Kazakhstan gbọ́ ẹjọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Andrey Korolyov, tí wọ́n dá lẹ́bi torí pé ó ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Ní June 1, 2017, Ilé Ẹjọ́ náà dá Ọ̀gbẹ́ni Korolyov láre, wọ́n sọ pé òmìnira ẹ̀sìn tó ní ti fún un lẹ́tọ̀ọ́ láti máa sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn láìfa wàhálà. Agbẹjọ́rò Àgbà fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn máa rí i pé àwọn èèyàn wọn yòókù rí irú ìdájọ́ tó tọ́ yìí gbà, àmọ́ látìgbà yẹn, àwọn ilé ẹjọ́ kéékèèké tó ń gbọ́ ẹjọ́ wọn ò gbà láti ṣe ohun tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe, wọ́n sì tún ti dá àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́bi pé wọ́n ń “ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì láì forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin.”
Gregory Allen, tó jẹ́ Igbá Kejì Agbẹjọ́rò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ó ká wa lára gan-an pé ohun táwọn aláṣẹ ṣe ní Rọ́ṣíà làwọn ti Kazakhstan náà ń ṣe, bí wọ́n ṣe ń fi ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ kan àwọn Ẹlẹ́rìí, tí wọn ò sì jẹ́ kí wọ́n lómìnira ẹ̀sìn, bẹ́ẹ̀, ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé fọwọ́ sí i pé wọ́n lómìnira ẹ̀sìn. Àfàìmọ̀ kó má lọ jẹ́ pé ohun tí ilé ẹjọ́ sọ ní June 29, pé kí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà dáwọ́ iṣẹ́ dúró, máa le ju bá a ṣe rò lọ. À ń retí pé kí wọ́n bá wa tún ẹjọ́ yìí dá bó ṣe tọ́, kí ohunkóhun má ṣèdíwọ́ fún wa.”
Kárí ayé ló ti ń ká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára pé ibi tọ́rọ̀ ń lọ yìí, pẹ̀lú ìgbésẹ̀ táwọn aláṣẹ ń gbé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àfàìmọ̀ kí wọ́n má fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Kazakhstan, bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà.