Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

APRIL 11, 2018
KAZAKHSTAN

Wọ́n Ti Dá Teymur Akhmedov Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n Lórílẹ̀-èdè Kazakhstan ní April 4, 2018

Wọ́n Ti Dá Teymur Akhmedov Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n Lórílẹ̀-èdè Kazakhstan ní April 4, 2018

Nursultan Nazarbayev tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan ní kí wọ́n dá Teymur Akhmedov sílẹ̀, wọ́n sì mú un kúrò látìmọ́lé ní April 4, 2018. Ṣáájú àkókò yẹn, ní March 27, 2018, àwọn aláṣẹ gba Arákùnrin Akhmedov láyè pé kó lọ ṣiṣẹ́ abẹ pàjáwìrì nílé ìwòsàn kan tó wà nílùú Almaty. Ibẹ̀ ló wà báyìí, tí ara rẹ̀ ti ń yá díẹ̀díẹ̀.

Arákùnrin Akhmedov, ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61), ti wà lẹ́wọ̀n láti January 18, 2017, torí pé ó kàn ń ṣe ohun tó gbà gbọ́. Inú ẹ̀ dùn pé òun ti pa dà sílé báyìí lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí òun.

Gbogbo wa là ń yọ̀ torí pé Jèhófà ti gba ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sílẹ̀.​—2 Sámúẹ́lì 22:2.