Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Hòtẹ́ẹ̀lì Dusit nílùú Nairobi, lórílẹ̀-èdè Kenya, tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

JANUARY 25, 2019
KENYA

Àwọn Adigunjalè Wá sí Hòtẹ́ẹ̀lì Kan ní Kenya

Àwọn Adigunjalè Wá sí Hòtẹ́ẹ̀lì Kan ní Kenya

Ní January 15, 2019, ó kéré tán, èèyàn mọ́kànlélógún (21) ló kú nígbà táwọn adigunjalè wá sí hòtẹ́ẹ̀lì àti ọ́fíìsì kan ní ìlú Nairobi, lórílẹ̀-èdè Kenya.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Kenya ròyìn pé kò sí ìkankan nínú àwọn akéde tó kú tàbí tó fara pa nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé tó ìrìn kìlómítà méje (máìlì mẹ́rin) sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Ó ju mẹ́wàá lára àwọn ará wa tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọgbà Dusit, táwọn adigunjalè náà ti ṣọṣẹ́. Lásìkò táwọn adigunjalè náà wá, méje lára àwọn ará náà ò sí níbi iṣẹ́; àwọn èèyàn tó kù sì jáde níbẹ̀ ní àlàáfíà. Arákùnrin kan àti arábìnrin kan tó fara pa mọ́ fún wákàtí méjìlá wà lára àwọn tí wọ́n kó jáde níbẹ̀ ní àlàáfíà.

Àwọn alàgbà ìjọ tó wà lágbègbè náà àtàwọn alábòójútó àyíká lo Bíbélì láti fún àwọn ará tí àjálù yìí ṣẹlẹ̀ sí níṣìírí, wọ́n sì fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa tu àwọn ará wa nínú lásìkò wàhálà yìí.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.