SEPTEMBER 4, 2019
KENYA
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Luo Lórílẹ̀-Èdè Kẹ́ńyà
Ní August 30 2019, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Luo ní àpéjọ agbègbè tó wáyé nílùú Kisumu, lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Arákùnrin Remy Pringle, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà ló mú Bíbélì yìí jáde lọ́jọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ náà. Àwọn tó wá sí àpéjọ náà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó wà níbi àpéjọ àgbègbè méjì míì tí àtagbà ètò náà dé, jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti mọ́kànlélọ́gọ́rin (2,481).
Nǹkan bí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi ṣiṣẹ́ lórí ìtúmọ̀ Bíbélì yìí kó tó parí. Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè tó ṣiṣẹ́ náà sọ pé: “Ó máa nípa tó pọ̀ lórí àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọn ti ń fojú sọ́nà fún Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lódindi lédè Luo. Ọ̀pọ̀ ìdílé tá a jọ wà nínú ìjọ ni kò le ra odindi Bíbélì fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé wọn. Torí náà, ìbùkún lèyí jẹ́ fún wọn láti ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan. Ìyẹn nìkan kọ́, èdè òde òní tá a fi túmọ̀ Bíbélì yìí á mú kó rọrùn láti lóye, bákan náà, á mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára bá a ṣe ń lò ó fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìjọsìn ìdílé.”
A ti túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lódindi tàbí ní apá kan sí èdè mẹ́rìnlélọ́gọ́sàn-án (184), mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) nínú wọn jẹ́ àtúnṣe lódindi, tá a gbé ka ẹ̀dà Gẹ̀ẹ́sì tá a tún ṣe lọ́dún 2013. Akéde tó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (1,800) ló ń sọ èdè Luo ní Kẹ́ńyà, ó sì dá wa lójú pé Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde yìí á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ Jèhófà. Á tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wàásù fún àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún tó ń sọ èdè Luo.—Mátíù 24:14.