Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

(Apá òsì) Gbọ̀ngàn kan ládùúgbò ni wọ́n ti ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ náà. (Apá ọ̀tún) Àwọn ilé méjì tá a fi ṣe ilé ẹ̀kọ́ náà

NOVEMBER 19, 2019
KENYA

A Ya Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run Kan Sí Mímọ́ ní Kẹ́ńyà

A Ya Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run Kan Sí Mímọ́ ní Kẹ́ńyà

Ní November 9, 2019, a ya ilé tuntun kan tá a kọ́ fún ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run sí mímọ́ ní Eldoret, lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Arákùnrin Bengt Olsson tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà ló sọ àsọyé ìyàsímímọ́ náà. Àwọn ẹgbẹ̀rún kan àti igba ó dín kan (1,199) títí kan ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tí wọ́n wá láti onírúurú ibi lórílẹ̀-èdè náà ló pésẹ̀ síbẹ̀. Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run (SKE) àti Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Àyíká Àtàwọn Ìyàwó Wọn la fẹ́ máa lo ibẹ̀ fún. Ó kéré tán, àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ SKE mẹ́rin la retí pé á máa kẹ́kọ̀ọ́ yege níbẹ̀ lọ́dọọdún.

Àwọn ilé tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ń lò tẹ́lẹ̀ àmọ́ tá a ti tún ṣe la sọ di ilé ẹ̀kọ́ yìí. Ilé táwọn míṣọ́nnárì ń gbé tẹ́lẹ̀ la sọ di ibi tí wọ́n á ti máa fọṣọ, ilé ìdáná àti ilé ìjẹun. A sì sọ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan di kíláàsì táwọn akẹ́kọ̀ọ́ á máa lò. April 1, 2019 la bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí, a sì parí èyí tó pọ̀ jù níbẹ̀ ní September 9.

Nígbà tí Arákùnrin Olsson ń sọ bí ilé ẹ̀kọ́ yìí ṣe ṣe pàtàkì tó, ó sọ pé: “Ẹ̀rí fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà ni wọ́n fẹ́ mọ Ọlọ́run. Ó dá wa lójú pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa gbà nílé ẹ̀kọ́ yìí á mú kí wọ́n túbọ̀ já fáfá láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rọ́ wá sórí òkè Jèhófà.”​—Míkà 4:1.