Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn arákùnrin wa ń ṣètò àwọn ìpèsè ìrànwọ́

JUNE 8, 2021
KÒLÓŃBÍÀ

Ètò Ìrànwọ́ Fáwọn Ará Wa ní Kòlóńbíà

Ètò Ìrànwọ́ Fáwọn Ará Wa ní Kòlóńbíà

Láti April 2021 ni rògbòdìyàn ti ń ṣẹlẹ̀ ní Kòlóńbíà. Kò sẹ́ni tó kú tàbí tó fara pa nínú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀. Àmọ́, kò rọrùn láti rí oúnjẹ àti epo pẹtiróòlù rà láwọn àgbègbè kan. Àwọn ará wa ń fara da ìṣòro ọ̀wọ́n oúnjẹ àti epo, àtèyí tí àjàkálẹ̀ ààrùn COVID-19 tó ń jà lọ́wọ́ ńfà.

Kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lè rí ìránwọ́ gbà lásìkò ìṣòro yìí, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Kòlóńbíà yan àwọn ìgbìmọ̀ márùn-ún kan gẹ́gẹ́ bí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Àjálù. Ìgbìmọ̀ yìí á máa pèsè ohun táwọn ará nílò, wọ́n á sì rí i dájú pé wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tá a jẹ́ kí wọ́n dènà ààrùn COVID-19. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó wà lágbègbè yẹn ń ran ara wọn lọ́wọ́, ní pàtàkì láti ra oúnjẹ. Àwọn alàgbà ìjọ àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò náà ń lo Bíbélì láti fáwọn ará níṣìírí.

Arákùnrin Almond Winklaar tó ń ṣèrànwọ́ fún ọ̀kan lára àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Àjálù sọ pé: “Nǹkan ò rọrùn fún wa rárá lásìkò yìí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe tètè bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lásìkò wàhálà yìí.”

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa rèé lẹ́yìn tí wọ́n gba àwọn oúnjẹ

Àwọn akéde méjìdínlógún (18) àtàwọn ìdílé wọn ló rí oúnjẹ gbà nínú ìjọ La Loma Arena. Àwọn tọkọtaya kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nínú ìjọ yẹn sọ pé: “Inú wa dùn gan-an, ayọ̀ wa kún nígbà tá a ráwọn ohun tí a nílò gbà látọ̀dọ̀ àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Àjálù. Jèhófà fi ohun tí wọn ṣe yìí dáhùn àdúrà wa. A dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n fún wa lóhun tá a nílò gan-an, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà náà tó fún wa lókun àti ẹ̀mí ìfaradà.”

Àwọn òṣìṣẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ilé ìtajà ńlá táwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Àjálù ti ra ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn ará nílò sọ̀rọ̀ tó wúni lórí gan-an nípa ètò ìrànwọ́ tá a ṣe yìí. Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtajà ńlá yẹn sọ pé: “Mo mọ̀ pé ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá sílé wa láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa, àmọ́ iṣẹ́ gidi tí ẹ̀ ń ṣe yìí láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́ mórí mi wú gan-an ni.”

Láìka àwọn ìṣòro táwọn ará wa ń dojú kọ sí, wọ́n ń bá a lọ láti jọ́sìn Jèhófà déédéé. A mọ̀ pé Jèhófà á máa pèsè ohun táwọn ará wa ọ̀wọ́n yìí nílò àti ìtùnú látinú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń bá a lọ láti má ṣe “jẹ́ apá kan ayé.”—Jòhánù 17:16.