Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ilé Ẹjọ́ Ìjọba Kòlóńbíà

JUNE 9, 2021
KÒLÓŃBÍÀ

Nínú Ẹjọ́ Pàtàkì Kan, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti Kòlóńbíà Gbà Pé Ọmọdé Tó Ti Gbọ́n Lè Ṣèpinnu Lórí Ọ̀rọ̀ Ìṣègùn

Nínú Ẹjọ́ Pàtàkì Kan, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti Kòlóńbíà Gbà Pé Ọmọdé Tó Ti Gbọ́n Lè Ṣèpinnu Lórí Ọ̀rọ̀ Ìṣègùn

Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti Kòlóńbíà gbé ìpinnu kan jáde ní April 7, 2021. Ìpinnu yìí dá ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì tójú bọ́, ó ní ẹ̀tọ́ láti pinnu irú ìtọ́jú ìṣègùn tó fẹ́ fúnra ẹ̀. Nínú ẹjọ́ yìí, aláìsàn náà sọ pé kí wọ́n lo ọ̀kan lára àwọn ìtọ́jú ìṣègùn tí kò la ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ lọ fún òun. Ilé Ẹjọ́ Ìjọba gbà pé tí irú ọmọ bẹ́ẹ̀ bá buwọ́ lu fọ́òmù kan láti fi sọ irú ìtọ́jú tó fẹ́ àti ẹni tó lè ṣèpinnu lórí ìlera òun, ẹnikẹ́ni ò gbọdọ̀ fojú kéré irú fọ́ọ̀mù bẹ́ẹ̀ torí pé ó fìdí múlẹ̀ lábẹ́ òfin àti pé ìyẹn ò fi hàn pé àwọn òbí ọmọ náà kò tọ́jú ọmọ wọn lọ́nà tó yẹ.

Arábìnrin Daniela Caicedo àti àwọn òbí rẹ̀

Ní May 27, 2020, dókítà sọ pé Arábìnrin Daniela ní àìsàn leukemia tó lágbára gan-an, ìyẹn àìsàn jẹjẹrẹ tó máa ń ba ẹ̀jẹ̀ jẹ́. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ni Daniela nígbà yẹn. Àwọn dókítà àtàwọn nọ́ọ̀sì fẹ́ fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára, kí wọ́n sì fún un ní ìtọ́jú tí wọ́n ń pè ní chemotherapy. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rẹ Daniela gan-an, ó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé fún wọn pé òun ò fẹ́ gbẹ̀jẹ̀ torí kò bá ìgbàgbọ́ òun tó dá lórí Bíbélì mu.—Ìṣe 15:29.

Ní June 24, 2020, Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ìdílé ní Kòlóńbíà (ICBF) fún àwọn dókítà àtàwọn nọ́ọ̀sì láṣẹ láti fẹ̀jẹ́ sí Daniela lára láìka pé ó ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé òun fẹ́ gbẹ̀jẹ̀. Àjọ yìí tún ní kí wọ́n ṣàyẹ̀wò ọpọlọ Daniela. Nígbà tí wọ́n ń ṣàyẹ̀wò yìí, arábìnrin wa fi hàn pé orí òun pé, òun sì dàgbà tó láti pinnu irú ìtọ́jú ìṣègùn tí òun fẹ́ gbà àtèyí tóun ò fẹ́. Èsì àyẹ̀wò ọpọlọ yẹn tún fi hàn pé kì í ṣe pé wọ́n fipá mú Daniela láti ṣe ìpinnu tó ṣe, àmọ́ ṣe ló wá látọkàn ẹ̀ torí ohun tó gbà gbọ́.

Adájọ kóòtù kékéré sọ pé lóòótọ́ Daniela ṣì kéré, àmọ́ orí ẹ̀ pé, ó sì lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé òun ò ní gba ẹ̀jẹ̀. Àmọ́, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rún sọ pé dókítà Daniela lè fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára tó bá rí i pé ó pọn dandan bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn àwọn òbí rẹ̀, Daniela pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba, kí wọ́n lè gbèjà ẹ̀tọ́ ẹ̀ láti má gba ẹ̀jẹ̀.

Nígbà tí wọ́n gbẹ́jọ́ yìí tán, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba gbèjà ẹ̀tọ́ tí Daniela ní. Ilé ẹjọ́ pinnu pé òmínira ẹ̀sin “máa ń fúnni láyè láti sún mọ́ Ọlọ́run àti láti ṣe ohun téèyàn mọ̀ pé kò ní múnú bí Ọlọ́run.” Láfikún, ilé ẹjọ́ sọ pé tí wọ́n bá fipá fún Daniela lẹ́jẹ̀, ó máa ba àlàáfíà tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, ó sì máa fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ àti ayọ̀ tó yẹ kó ní dù ú. Ilé ẹjọ́ tún pinnu pé Daniela lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìtọ́jú tó bá fẹ́, tó fi mọ́ àwọn oríṣiríṣi ìtọ́jú ìṣègùn tí kò la ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ lọ.

Ìpinnu pàtàkì yìí fi hàn pé àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ọmọdé tí wọ́n sì ti gbọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìtọ́jú tí kò ta ko ìgbàgbọ́ wọn, ojúṣe àwọn dókítà àtàwọn nọ́ọ̀sì sì ni láti bọ̀wọ̀ fún ìpinnu tí wọ́n bá ṣe. Ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àwọn agbẹjọ́rò tó ṣẹjọ́ yìí sọ pé: “Ilé Ẹjọ́ Ìjọba gbà pé béèyàn ṣe lẹ́tọ̀ọ́ láti wà láàyè náà lo ṣe lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ohun tó máa fún un láyọ̀, ì báà tiẹ̀ jẹ́ ọmọdé. Fún ìdí yìí, tá a bá fẹ́ káwọn ọmọdé tó ti gbọ́n láyọ̀ láyé wọn, àfi ká bọ̀wọ̀ fún ohun tí wọ́n gbà gbọ́, kódà táwọn adájọ́ tàbí àwọn dókítà ò bá tiẹ̀ fara mọ́ ìgbàgbọ́ wọn.”

Lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba kéde ìpinnu náà, Daniela sọ pé: “Ohun tó múnú mi dùn jù ni bí ẹ̀jọ́ yìí ṣe gbé orúkọ Jèhófà ga. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kọ́ mi pé Jèhófà lè gba àwọn ìṣòro kan láyè ká lè fi bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó hàn.”

Ara Daniela ti ń yá díẹ̀díẹ̀, ìtọ́jú tó dára gan-an ló sì ń gbà. Ó máa lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní August 2021. Ó dá wa lójú pé inú Ọlọ́run wa, Jèhófà máa ń dùn bó ṣe ń wo àwọn ọ̀dọ́ tó ń fi ìwà wọn bọlá fún un.—Sáàmù 148:12, 13.