Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń lọ lọ́wọ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n Barranquilla.

APRIL 26, 2019
KÒLÓŃBÍÀ

Wọ́n Fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìwé Ẹ̀rí Torí Bá A Ṣe Ń Kọ́ Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Kòlóńbíà

Wọ́n Fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìwé Ẹ̀rí Torí Bá A Ṣe Ń Kọ́ Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Kòlóńbíà

Ìwé ẹ̀rí tí àjọ Paulo Freire Educational Center fi mọyì ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń ṣe ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní ìlú Valledupar.

Ó ti lé ní ogun (20) ọdún báyìí táwọn ará wa ti ń kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ ní kòlóńbíà. Ní November 30, 2018, àjọ Paulo Freire Educational Center fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìwé ẹ̀rí kan láti kan sáárá sí wa torí bá a ṣe ń kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní ìlú Valledupar. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àádọ́ta (50) lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà níbẹ̀ ló ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Káàkiri orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà, ọgbà ẹ̀wọ̀n márùndínláàádọ́rin (65) làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, iye àwọn tá a sì ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje àti méjìlélọ́gọ́rin (782). Látọdún 1996, iye àwọn tó ṣèrìbọmi lára wọn ti di ọgọ́ta (60).

Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni Néver Antonio Cavadía ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti di alàgbà nínú ìjọ rẹ̀ báyìí. Òun rèé pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, Lety Cavadía.

Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni Néver Antonio Cavadía ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi ní 1998. Nígbà tó yá, wọ́n tú u sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní ìlú Valledupar lọ́dún 2007. Nígbà tó ń mẹ́nu kan àǹfààní tí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe fóun, ó ní: “Àwọn ìlànà Bíbélì dáàbò bò mí, ó sì jẹ́ kí n ní ọgbọ́n tó wúlò nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n. Ó tún mú kí n ṣe àwọn ìyípadà tó lágbára nínú ayé mi, kí n sì nírètí.”

Gbogbo ìsapá wa láti kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé bá ìfẹ́ Jèhófà mu pé, “ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:4.