Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JANUARY 1, 2019
KYRGYZSTAN

Ìtẹ̀síwájú Lórí Ọ̀ràn Ẹjọ́ Nílùú Osh, Lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan

Ìtẹ̀síwájú Lórí Ọ̀ràn Ẹjọ́ Nílùú Osh, Lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan

Ní November 30, 2018, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan forúkọ ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Osh sílẹ̀, ìlú yìí ló tóbi ṣèkèjì lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan.

Àwọn ará wa jọlá bí ìjọba àpapọ̀ ṣe forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ ní Kyrgyzstan látọdún 1998, àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbé òfin kan nípa ẹ̀sìn jáde lọ́dún 2008, léraléra ni àwọn aláṣẹ tó wà láwọn ìlú ní agbègbè gúúsù orílẹ̀-èdè náà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ̀ láti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀, apá ibẹ̀ sì ni ìlú Osh wà. Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn aláṣẹ ìlú bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìpàdé àwọn ará wa àti iṣẹ́ ìwàásù wọn sí ohun tí kò bófin mu. Láwọn ìgbà kan àwọn ọlọ́pàá ya wọnú ilé tàbí ibi táwọn ará gbà láti pé jọ sí fún jọ́sìn.

Inú wa dùn pé ìyípadà yìí máa mú kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà túbọ̀ lẹ́tọ̀ọ́ lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan láti máa pé jọ fún ìjọsìn ká sì máa báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì láìsí wàhálà.—1 Tímótì 2:1-4.