Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 14, 2020
LEBANON

Nǹkan Bú Gbàù Nílùú Beirut, ní Lebanon

Nǹkan Bú Gbàù Nílùú Beirut, ní Lebanon

Ní August 4, 2020, nǹkan kan bú gbàù lọ́nà tó rinlẹ̀ gan-an níbi táwọn ọkọ̀ òkun máa ń gúnlẹ̀ sí nílùú Beirut tó jẹ́ olú-ìlú Lebanon. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló fara pa, àwọn ohun tó sì bà jẹ́ kọjá àfẹnusọ. Ilé ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló bà jẹ́. Ó sì dùn wá pé àwọn ará wa kan fara pa gan-an, àmọ́ ìkankan nínú wọn ò kú.

A mọ̀ pé Ọlọ́run wa aláàánú á máa pèsè ìrànwọ́ èyíkéyìí táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá nílò.​—2 Sámúẹ́lì 22:3.