Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JANUARY 25, 2018
MADAGASCAR

Ìjì Cyclone Ava Kọlu Madagásíkà

Ìjì Cyclone Ava Kọlu Madagásíkà

Ní January 5, 2018, ìjì líle Cyclone Ava kọlu orílẹ̀-èdè Madagásíkà. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ròyìn pé nǹkan bí èèyàn mọ́kànléláàádọ́ta [51] ló kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló sì ti di ẹni tí kò nílé lórí mọ́.

Ìròyìn tá a gbọ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wà ní Madagásíkà jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí ọ̀kankan nínú àwọn ará wa tó kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Àmọ́ ilé márùndínláàádọ́ta [45] ló ti bà jẹ́, títí kan Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́fà. Ìjì yẹn tún ba ohun ọ̀gbìn jẹ́, ohun tí púpọ̀ nínú àwọn ará wa sì fi ń gbọ́ bùkátà ara wọn nìyẹn. A ṣètò pé kí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù bójú tó àwọn ará tí àjálù náà bá, wọ́n pèsè oúnjẹ, aṣọ, wọ́n tún ṣètò ibi táwọn ará lè forí pamọ́ sí fún ìgbà díẹ̀. Àwọn arákùnrin méjì láti ẹ̀ka ọ́fíìsì tún rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ láti ṣe ìpàdé àkànṣe pẹ̀lú àwọn tí àjálù náà dé bá, wọ́n fi Bíbélì gbé wọn ró.

Owó táwọn ará wa kárí ayé fi ṣe ìtìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí lò láti pèsè ìrànwọ́ fáwọn ará wa tí àjálù dé bá kárí ayé, irú èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Madagásíkà. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa báa lọ láti jẹ́ orísun ààbò fáwọn ará wa ní Madagásíkà lásìkò tó nira yìí.​—Sáàmù 9:​9, 10

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Madagascar: Rinera Rakotomalala, +261-33-37-012-91