Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ó ju ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì (42,000) akéde tó yọ̀ǹda ara wọn títí wọ́n fi parí ètò ìrànwọ́ ní Amẹ́ríkà Àárín.

APRIL 12, 2019
MEXICO

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Parí Ètò Ìrànwọ́ ní Amẹ́ríkà Àárín Lẹ́yìn Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Wáyé

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Parí Ètò Ìrànwọ́ ní Amẹ́ríkà Àárín Lẹ́yìn Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Wáyé

Lọ́dún 2017, ìmìtìtì ilẹ̀ méjì tó lágbára wáyé lórílẹ̀-èdè Guatemala àti Mẹ́síkò. Àwọn ará wa parí ètò ìrànwọ́ tí wọ́n ṣe ní gbogbo agbègbè náà lóṣù December 2018.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Amẹ́ríkà Àárín bẹ̀rẹ̀ ètò ìrànwọ́ yìí nígbà tí wọ́n ṣe onírúurú ìpàdé láti fún àwọn ará tí àjálù náà ṣẹlẹ̀ sí níṣìírí. Wọ́n ṣe ìpàdé náà ní ìpínlẹ̀ Chiapas, Morelos, Oaxaca, àti Puebla, kódà wọ́n tún ṣe é ní ìlú Mexico City. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka dá ìgbìmọ̀ mọ́kàndínlógójì (39) tó ń ṣètò ìrànwọ́ sílẹ̀, àwọn ìgbìmọ̀ yìí ló sì ṣètò bí wọ́n ṣe tún gbogbo àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe.

Arákùnrin Jesse Pérez, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Amẹ́ríkà Àárín bá àwọn akéde tí àjálù náà kàn ṣèpàdé ní ìpínlẹ̀ Morelos.

Arákùnrin méjì ń ṣiṣẹ́ lórí òrùlé Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan tí wọ́n tún kọ́ nígbà ètò ìrànwọ́ náà.

Lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ó ju ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì (42,000) akéde tó yọ̀ǹda ara wọn láti ìpínlẹ̀ mẹ́wàá kí wọ́n lè bá àwọn tó ń ṣètò ìrànwọ́ ṣiṣẹ́. Àwọn ará yìí tún ilé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mọ́kàndínlógún (619) kọ́ pẹ̀lú Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ méjì. Wọ́n tún ṣàtúnṣe sí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé méjì (502) ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́tàléláàádọ́ta (53). Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ilé mẹ́wà kọ́ ní Guatemala.

Ara àwọn tí wọ́n ṣèrànlọ́wọ́ fún ni ìdílé Hernández àti Santiago.

Ìdílé Hernández níwájú ilé wọn, àwọn tó ṣètò ìrànwọ́ ló bá wọn tún ilé náà kọ́.

Ìlú Chalco ni ìdílé Hernández ń gbé, ibẹ̀ ò ju ogójì (40) kìlómítà sí ìlú Mexico City. Ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé ní September 19, 2017 ba ilé wọn jẹ́ kọjá àtúnṣe. Arábìnrin Ana María Hernández sọ pé: “Ní gbogbo àsìkò wàhálà yìí, a ò ṣaláìní ohunkóhun tá a nílò. Àwọn ará tọ́jú wa gan-an. Mo ṣì rántí bí ilé wa tẹ́lẹ̀ ṣe rí nígbà tó wó, àmọ́ tí nǹkan bí àádọ́ta àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn wá láti bá wa kọ́ ilé wa tuntun. Títí dòní, ohun táwọn ará yẹn ṣe fún wa ṣì máa ń ya àwọn ará àdúgbò wa lẹ́nu.” Yàtọ̀ sí ìrànlọ́wọ́ tí ìdílé Hernández rí gbà yìí, aṣojú kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Amẹ́ríkà Àárín wá sọ́dọ̀ wọn, ó sì fi Bíbélì fún wọn níṣìírí.

Ìdílé Santiago níwájú ilé wọn tuntun.

Ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé ní September 7, 2017 kan ìdílé Santiago tó ń gbé ní ìlú Juchitán, ìpínlẹ̀ Oaxaca. Ó ba ilé wọn jẹ́ débi pé kò ṣeé gbé mọ́. Àmọ́ láàárín oṣù mẹ́fà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìrànwọ́ bá wọn kọ́ ilé tuntun míì. Olórí ìdílé náà, Arákùnrin Victor Santiago sọ pé: “Bí ètò Jèhófà ṣe yára pèsè àwọn ohun tá a nílò fún wa wú mi lórí púpọ̀. Mo rí i pé ọwọ́ Jèhófà la wà, òun ló sì ń bójú tó wa.”

Arákùnrin Jesse Pérez, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Amẹ́ríkà Àárín, sọ pé: “Ọṣẹ́ ti ìmìtìtì ilẹ̀ méjèèjì tó wáyé ṣe pọ̀ gan-an. Àmọ́ ètò ìrànwọ́ tó wúlò tá a ṣe tẹ̀ lé e fún àwọn ará láǹfààní láti yọ̀ǹda ara wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akéde ló ṣèrànlọ́wọ́, èyí sì fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. Inú wa dùn gán-an pé Jèhófà ti bù kún ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìrànwọ́ yìí.’”—2 Kọ́ríńtì 8:1-4.