Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 17, 2020
MEXICO

Ìjì Líle Hurricane Hanna Jà Dé Mẹ́síkò

Ìjì Líle Hurricane Hanna Jà Dé Mẹ́síkò

Ibi tó ti ṣẹlẹ̀

Ìpínlẹ̀ Tamaulipas àti Nuevo León, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

Àjálù

  • Ọwọ́ ìjì náà le gan-an nígbà tó yá, ó fẹ́ wọ àríwá ìlà oòrùn Mẹ́síkò ní July 26, 2020, ó sì fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ omiyalé

Ìpalára tó ṣe fáwọn ará wa

  • Ní ìpínlẹ̀ Nuevo León, ìdílé mẹ́rìnlá (14) ló kúrò nílé wọn kí ìjì náà tó dé ọ̀dọ̀ wọn

  • Nílùú Reynosa, ní ìpínlẹ̀ Tamaulipas, ọgọ́rùn-ún (100) akéde ni ìjì náà mú kí wọ́n fi ilé sílẹ̀

Àwọn ohun tó bà jẹ́

  • Ilé mọ́kànlélógún (21) ló bà jẹ́ ní ìpínlẹ̀ Nuevo León

  • Ilé mẹ́tàdínlọ́gọ́fà (117) ló bà jẹ́ ní ìpínlẹ̀ Tamaulipas

Ètò ìrànwọ́

  • Ẹ̀ka ọ́fíìsì Central America ti yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù

  • Àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ìjọ tó wà lágbègbè tí ìjì náà ti ṣọṣẹ́ ń ṣètò tó yẹ kí wọ́n lè rí i pé àwọn ṣàtúnṣe àwọn ilé tí omi wọ̀, kí àwọn ilé náà lè wà ní mímọ́ tónítóní

  • Ní ìpínlẹ̀ Nuevo León, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ará tó kúrò nílè ló ti pa dà sílé wọn

  • Ní ìpínlẹ̀ Tamaulipas, àwọn ìjọ tó wà lágbègbè náà ń fún àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí ní oúnjẹ àti aṣọ

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ìkankan nínú àwọn ará wa ò fara pa nígbà àjálù yìí. Ètò ìrànwọ́ táwọn ará yìí ń jàǹfààní ẹ̀ fi hàn pé ìgbà gbogbo ni Baba wa ọ̀run àtàwọn èèyàn ẹ̀ máa ń pèsè “ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.”​—Sáàmù 46:1.