Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 2, 2022
MEXICO

A Mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Tlapanec

A Mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Tlapanec

Ní February 27, 2022, Arákùnrin Carlos Cázares, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Central America, mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Tlapanec. Ní báyìí, àwọn ará lè rí i kà lórí ẹ̀rọ, àmọ́ a máa tẹ̀ ẹ́ sórí ìwé kí ọdún yìí tó parí. A gba àsọyé tí wọ́n fi mú Bíbélì náà jáde sílẹ̀, àwọn tó gbádùn ẹ̀ sì tó ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti ogún (820).

July 2020 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì náà, lásìkò tí àrùn Corona le gan-an. Atúmọ̀ èdè kan sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro la dojú kọ lẹ́nu iṣẹ́ náà, ó yà wá lẹ́nu gan-an pé a lè parí ẹ̀ láàárín ọdún kan ààbọ̀. Ó dájú pé Jèhófà ló mú kíṣẹ́ náà yára kánkán.”

Ìlú Tlapa tó wà ní ìpílẹ̀ Guerrero lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ni ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè Tlapanec wà. Àjà mẹ́ta àkọ́kọ́ tó wà lápá òkè ilé ńlá kan làwọn atúmọ̀ èdè náà ti ń ṣiṣẹ́

Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú Bíbélì tuntun náà rọrùn láti lóye. Àpẹẹrẹ kan lèyí tó wà ní Mátíù 5:3. Ohun tó wà nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ ni: “Aláyọ̀ ni àwọn tó mọ̀ pé àwọn ò lè ṣe ohunkóhun láìsí pé ẹ̀mí mímọ́ ran àwọn lọ́wọ́,” tàbí “Aláyọ̀ ni àwọn tí kò lera ní ẹ̀mí.” Àmọ́, Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn wá Ọlọ́run.”

Ìtumọ̀ Bíbélì yìí máa wúlò gan-an fáwọn ará lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nínú àsọyé tí Arákùnrin Cázares sọ, ó sọ pé: “Ọlọ́run Olódùmarè fẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere ní èdè wọn, ìyẹn èdè tí wọ́n ń sọ lójoojúmọ́, kì í ṣe ní èdè tó máa nira fún wọn láti lóye.”

A bá àwọn ará wa tí wọ́n ń sọ èdè Tlapanec yọ̀ gan-an pé wọ́n ní Bíbélì tuntun yìí, inú wa sì dùn bá a ṣe jọ ń sin Jèhófà “ní ìṣọ̀kan.”​—Sefanáyà 3:9.