JUNE 23, 2021
MEXICO
A Mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde ní Èdè Chol
Ní June 20, 2021, Arákùnrin Robert Batko tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Central America mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Chol. Wọ́n mú Bíbélì yìí jáde ní ẹ̀dà ti orí ẹ̀rọ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wọ́n gbà sílẹ̀, tí wọ́n sì ṣàtagbà rẹ̀ sáwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800).
Àwọn Ìsọfúnni Pàtàkì Nípa Iṣẹ́ Náà
Ìlú Chiapas lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń sọ èdè Chol ń gbé
Wọ́n fojú bù ú pé àwọn tó ń sọ èdè Chol máa tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba (200,000)
Àwọn akéde tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ló wà láwọn ìjọ méjìlélógún (22) àti àwùjọ méjì tó ń fi èdè Chol ṣèpàdé
Ọdún méjì àti oṣù mẹ́ta làwọn atúmọ̀ èdè mẹ́ta fi ṣiṣẹ́ lórí ìtúmọ̀ Bíbélì yìí
Arákùnrin kan tó ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì yìí sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tá a sábà máa ń lò lójoojúmọ́ ní wọ́n lò nínú ìtumọ̀ Bíbélì tuntun yìí. Orí kọ̀ọ̀kan tí mò ń kà ni mo sì gbádùn.”
Arákùnrin míì sọ pé: “Mo lè ka Bíbélì lédè Sípáníìṣì, àmọ́ inú mi dùn gan-an nígbà tí mo ka Bíbélì yìí lédè Chol, tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ mi. Ṣe ló dà bí ìgbà tí mo ń jẹ oúnjẹ aládùn tí ìyá mi sè.”
A mọ̀ pé Bíbélì yìí máa ran àwọn ará wa tó ń sọ èdè Chol lọ́wọ́ láti rí “àwọn ìṣúra tó fara sin” nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Òwe 2:4, 5.