NOVEMBER 1, 2019
MEXICO
A Mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Maya
October 25, 2019 jẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé fún ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (6,500) àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ń sọ èdè Maya. Ọjọ́ yẹn la mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Maya. Arákùnrin Esteban Bunn tó jẹ́ ara ìgbìmọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì Central America ló mú Bíbélì yìí jáde ní àpéjọ agbègbè tí a ṣe ní Mérida, nílùú Yucatán lórílẹ̀-èdè Mexico. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà wáyé ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní Mérida, a sì ṣe àtagbà rẹ̀ sí pápá ìṣeré Poliforum Zamná. Bíbélì tá a mú jáde yìí máa wúlò gan-an fún àwọn ará wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nítorí pé àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje (762,000) ló ń sọ èdè Maya ni Mexico àti Amẹ́ríkà.
Ṣáájú àkókò yìí, Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun nìkan ló wà lédè Maya. December 14, 2012 la mú u jáde. Látìgbà yẹn, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29,000) ẹ̀dà tí a ti tẹ̀ jáde.
Atúmọ̀ èdè kan ṣàlàyé pé: “Èyí tó pọ̀ jú lára àwọn tó ń sọ èdè Maya ló mọyì Bíbélì gan-an, wọ́n sì gbà pé ohun tó bá sọ labẹ́ gé. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ló nira fún láti lóye ohun tí wọ́n bá kà lédè Maya. Torí náà, a rí i dájú pé èdè tó rọrùn, tí àwọn èèyàn ń sọ lójoojúmọ́ la lò.”
Ìṣòro kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí àwọn tó túmọ̀ Bíbélì náà ní ni pé bí wọ́n ṣe ń sọ èdè náà yàtọ̀ síra láti agbègbè kan sí òmíì. Torí náà, àkòrí tó rọrùn ni wọ́n lò fún èèpo iwájú ìwé náà, ìyẹn ni Biblia ich maya, tó túmọ̀ sí “Bíbélì Lédè Maya.” Bákàn náà, Bíbélì yìí ní àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000). Àwọn kan lára àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé yìí la fi kọ oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n ń gbà pé àwọn ọ̀rọ̀ kan kí gbogbo àwọn tó ń sọ èdè Maya lè lóye ohun tá à ń sọ dáadáa.
Láìsí àníàní, Bíbélì tuntun yìí jẹ́ “oúnjẹ ní àkókò tó yẹ,” ìyẹn oúnjẹ tẹ̀mí tó máa ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ń sọ èdè Maya lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn àti nígbà tí wọ́n bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́.—Mátíù 24:45.