Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 31, 2019
MEXICO

A Mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Tzotzil

A Mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Tzotzil

Ní October 25, 2019, arákùnrin Armando Ochoa tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Central America mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Tzotzil, níbi àpéjọ agbègbè tó wáyé ní gbọ̀ngàn tí wọn ń pè ní Poliforum of Tuxtla Gutiérrez nílùú Chiapas, lórílẹ̀-èdè Mexico. A sì ṣe àtagbà fídíò ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí gbọ̀ngàn tá a ń pé ní Centro de Convenciones. Àpapọ̀ gbogbo àwọn tó pésẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta, ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàdínláàádọ́ta (3,747).

A ti kọ́kọ́ mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun lédè Tzotzil jáde ní December 26, 2014, a sì ti pín in fún àwọn tó ń sọ èdè Tzotzil tó ń gbé ní agbègbè olókè àti làwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Chiapas lórílẹ̀-èdè Mexico. Nínú àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Mexico tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún (16,000,000), nǹkan bí ìlàjì mílíọ̀nù (500,000) làwọn tó ń sọ èdè Tzotzil, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mẹ́rìnlá (2,814) sì wà lára wọn.

Àwọn atúmọ̀ èdè Tzotzil kojú ọ̀pọ̀ ìpèníjà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìwé díẹ̀ ló wà lédè Tzotzil, àwọn ìwé atúmọ̀ èdè náà ò sì pọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, èdè àdúgbò méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà nínú èdè yìí. Torí náà, àwọn atúmọ̀ èdè ní láti wá bí wọ́n á ṣe lo ọ̀rọ̀ tó jẹ́ pé gbogbo àwọn tó ń sọ èdè Tzotzil pátá ló máa lóye ẹ̀.

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè ṣàkíyèsí pé: “Nítorí pé a lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà nínú Bíbélì yìí, ó máa ran àwọn tó bá kà á lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì méjì míì tó wà ní èdè Tzotzil lo orúkọ Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo níbi àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé kan nínú ìwé Ẹ́kísódù. Èyí ni Bíbélì àkọ́kọ́ ní èdè Tzotzil tó máa dá orúkọ Ọlọ́run padà sí gbogbo ibi tó yẹ kó wà.” Akéde kan tó ń sọ èdè Tzotzil tún fi kún un pé: “Àwọn Bíbélì míì ní èdè Tzotzil wọ́n gan-an. Èèyàn díẹ̀ ló sì le rówó rà á. Àmọ́, gbogbo èèyàn ló máa lè ní Bíbélì yìí láì ná wọn lówó.”

Láìsí iyè méjì, Bíbélì tuntun yìí máa wúlò fún gbogbo àwọn tó ń sọ èdè Tzotzil tí wọn sì “ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”​—Mátíù 5:3.