Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn mọ́tò tí wọ́n dáná sun lásìkò rògbòdìyàn tó wáyé nílùú Culiacán

NOVEMBER 8, 2019
MEXICO

Wọ́n Pa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kan Nígbà Rògbòdìyàn Tó Wáyé Nílùú Culiacán, Mexico

Wọ́n Pa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kan Nígbà Rògbòdìyàn Tó Wáyé Nílùú Culiacán, Mexico

Ní October 17, 2019, àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò orílẹ̀-èdè Mexico fìjà pẹẹ́ta pẹ̀lú àwọn tó ń ta oògùn olóró tí wọ́n ní àwọn ìbọn ńláńlá lọ́wọ́. Ìlú Culiacán Sinaloa ní Mexico ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé, àwọn tó ń gbé ìlú yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan. Lásìkò tí wọ́n fi ń rọ̀jò ìbọn síra wọn yìí, ọ̀pọ̀ ojú ọ̀nà ni wọ́n dí pa, wọ́n dáná sun ọ̀pọ̀ mọ́tò, àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan sì fìyẹn sá lọ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kan tó wà nítòsí. Àwọn aláṣẹ sọ pé ó kéré tán, èèyàn mẹ́rìnlá (14) ló kú. Ó dùn wá gan an nígbà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Central America ròyìn pé arákùnrin Noé Beltrán wà lára àwọn tó kú.

Noé Beltrán àti méjì lára àwọn ọmọ rẹ̀

Ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì (39) ni arákùnrin Beltrán, ó lọ́mọ mẹ́ta, ibi iṣẹ́ ló sì wà nígbà tí ìbọn ṣàdéédéé lọ bà á. Àwọn ará tó wà ládùúgbò yẹn àti alábòójútó àyíká wọn ti ń pèsè ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́ fún arábìnrin Rocío àtàwọn ọmọ wọn.

Àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ló wà ní ìjọ ọgọ́rin (80) tó wà nílùú Culiacán. Àwọn ìjọ kan yí àsìkò ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ àti ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá wọn pa dà lásìkò rògbòdìyàn yìí. Ilé làwọn ará kan ti dara pọ̀ mọ́ ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ náà lórí ẹ̀rọ alátagbà. Àwọn alábòójútó àyíká ń mú ipò iwájú nínú ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ yìí kó ìpayà bá.

Ikú Arákùnrin Beltrán dùn wá gan an, àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa báa nìṣó láti ti Arábìnrin Beltrán àti àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn. À ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí àlááfíà máa gbayé kan tí “inú dídùn gidigidi” yóò sì rọ́pò ìbànújẹ́​—Máàkù 5:42.