Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 15, 2018
MEXICO

Ìjì Líle Jà Tẹ̀ Léra ní Mẹ́síkò

Ìjì Líle Jà Tẹ̀ Léra ní Mẹ́síkò

Ní October 23, àjálù méjì ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ìyẹn ni Ìjì Vicente àti Ìjì Líle Willa. Ìjì Vicente fa omíyalé tó lágbára, ó sì mú kí ẹrẹ̀ ya ní gúúsù Mẹ́síkò débi pé ó pa èèyàn mọ́kànlá (11). Ìjì líle Willa ṣọṣẹ́ gan-an ní etí Òkun Pàsífíìkì ní Mẹ́síkò, òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá rọ̀, ọwọ́ atẹ́gùn ibẹ̀ sì le gan-an. Èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé igba àti àádọ́ta (4,250) ló sì sá kúrò nílé torí ìjì líle náà.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì Central America, tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mẹ́síkò, ròyìn pé kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó kú, wọn ò sì fara pa nígbà tí ìjì méjèèjì jà. Àmọ́ ní ìpínlẹ̀ Nayarit, akéde méjìdínlọ́gọ́fà (118) ló sá kúrò nílé lọ sí agbègbè olókè. Nílùú Sinaloa, omi ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan àti ilé ọ̀pọ̀ àwọn ará. Omi tún ya wọ ilé àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà márùn-ún nílùú Michoacán. Àmọ́ àwọn ará tó wà níbẹ̀ ṣàtúnṣe tó yẹ sí ilé wọn àti Gbọ̀ngàn Ìjọba tí omi wọ̀ náà.

Àdúrà wa ni pé kí àwọn ará wa tí àwọn ìjì yìí ṣe ní jàǹbá ní Mẹ́síkò máa fara dà á, kí wọ́n sì máa rántí pé gbogbo wa la jọ ń retí ọjọ́ iwájú tí àjálù ò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.—2 Kọ́ríńtì 6:4.