Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 12, 2017
MEXICO

Ìjì Tí Wọ́n Pè Ní Lidia Jà ní Orílẹ̀-Èdè Mẹ́síkò

Ìjì Tí Wọ́n Pè Ní Lidia Jà ní Orílẹ̀-Èdè Mẹ́síkò

Ìjì kan tí wọ́n pè ní Lidia jà ní Ìyawọlẹ̀ Omi Baja California lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ní September 1. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rọlẹ̀ nígbà tó fi máa di ọjọ́ Saturday, síbẹ̀ òjò tó rọ̀ pọ̀ gan-an, kò tíì sí irú ẹ̀ láti ọdún 1933. Ó kéré tán, èèyàn márùn-ún ló kú nínú ìjì náà.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Mexico City fi tó wa létí pé arábìnrin Ẹlẹ́rìí kan kú, ọ̀gbàrá òjò tó ń ya mù-ún mù-ún ló gbé e lọ nígbà tó ń rìn lọ sílé. Ọ̀gbàrá yẹn gbé àwọn mẹ́ta míì lọ, àmọ́ wọ́n rí wọn yọ nínú ẹ̀. Láfikún sí i, ìjì náà ba ilé mẹ́jọ jẹ́ pátápátá. Gbogbo àwọn tí àjálù yìí ṣẹlẹ̀ sí ló rí ìtọ́jú gbà látọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tàbí látọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò wọn.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń bójú tó ètò ìrànwọ́ nígbà àjálù láti oríléeṣẹ́ wọn, ọrẹ táwọn èèyàn fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé ni wọ́n sì ń lò.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Mexico: Gamaliel Camarillo, +52-555-133-3048