Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 20, 2017
MEXICO

Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 7.1 wáyé ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 7.1 wáyé ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

Ní September 19, 2017, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára gan-an tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 7.1 wáyé ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ó sì pa èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì [200]. Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Central America rèé:

Ó dùn wá gan-an pé ọ̀kan lára àwọn arábìnrin wa ní Mexico City kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Arábìnrin kan tún wà tí a ṣì ń wá títí di báyìí lẹ́yìn tí ilé rẹ̀ wó. Arábìnrin kan fara pa yánayàna ní ìlú kan tó ń jẹ́ Puebla, a tún gbọ pé arábìnrin míì fara gbọgbẹ́ ó sì wà nílé ìwòsàn ní State of Mexico.

A kọ́kọ́ kó ìdílé Bẹ́tẹ́lì kúrò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, àmọ́ wọ́n ti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ báyìí. A dúpẹ́ pé ẹnikẹ́ni ò fara pa, ọ́fíìsì náà ò sì bà jẹ́.

À ń bá a lọ láti máa gbàdúrà fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa bá a ṣe ń gbé ní àkókò tó le koko yìí, ó dájú pé Jèhófà mọ “wàhálà ọkàn” wọn, á sì bójú tó wọn.—Sáàmù 31:7.

Media Contacts:

International: David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000

Mexico: Gamaliel Camarillo, +52-555-133-3048