APRIL 24, 2015
MEXICO
A Mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Tzotzil Lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò
MEXICO CITY—Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Tzotzil ní àpéjọ àgbègbè kan tá a ṣe ní December 26-28, 2014, nílùú Tuxtla Gutierrez, ìpínlẹ̀ Chiapas. Èdè Tzotzil tí àwọn ẹ̀yà Maya ń sọ la fi ṣe Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Kọ́kọ́ Máa Wá Ìjọba Ọlọ́run!” Wọ́n wá ṣe àtagbà rẹ̀ sí Comitan, Chiapas. Yàtọ̀ sí Bíbélì yẹn, gbogbo àwọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé mẹ́tàléláàádọ́rin [5,073] tó wà ní ìpàdé náà tún gba ìwé tuntun mẹ́fà míì tí wọ́n mú jáde lédè Tzotzil.
Gamaliel Camarillo tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé: “Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún wa bá a ṣe mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Tzotzil. Ojú wa ti wà lọ́nà láti fún àwọn aládùúgbò wa tó ń sọ èdè Tzotzil ní Bíbélì náà.”
Bí Iléeṣẹ́ Ètò Ẹ̀kọ́ lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ṣe sọ, àwọn tó ń sọ èdè Tzotzil tó ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógún ààbọ̀ [350,000] ní ìlú Baja California, Campeche, Chiapas, Oaxaca, àti Veracruz. Ká lè wàásù ìhìnrere fún àwọn tó ń sọ èdè Tzotzil, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣí ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè sí ìlú San Cristobal de las Casas, ní ìpínlẹ̀ Chiapas. Àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló ń túmọ̀ èdè Tzotzil ní ọ́fíìsì náà. Ọdún 2002, làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ mú ìwé jáde lédè Tzotzil. Ní báyìí, a ti ní ìwé tó lé ní ọgọ́ta [60] táwọn èèyàn lè wà jáde ní èdè Tzotzil láti ìkànnì wa, ìyẹn jw.org.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000
Mẹ́síkò: Gamaliel Camarillo, tẹlifóònù +52 555 133 3048