DECEMBER 1, 2017
MEXICO
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ṣe Tán Láti Bẹ̀rẹ̀ Àtúnṣe Sáwọn Ilé Tí Ìmìtìtì Ilẹ̀ Bà jẹ́ ní Guatemala àti Mexico
MEXICO CITY—Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti Central America máa bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe tó pọ̀ gan-an ní Guatemala àti Mexico ní December 1, 2017, láti pèsè ìrànwọ́ síwájú sí i nítorí ìmìtìtì ilẹ̀ méjì tó wáyé ní oṣù September. Gbàrà lẹ́yìn tí ìmìtìtì ilẹ̀ yẹn ti wáyé ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ṣètò ìrànwọ́, wọ́n pèsè omi, oúnjẹ, oògùn àti aṣọ fáwọn arákùnrin wa tí àjálù yẹn dé bá. Ohun míì tí wọ́n tún máa bẹ̀rẹ̀ báyìí ni bí wọ́n ṣe máa tún Gbọ̀ngàn Àpéjọ, Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ilé àwọn arákùnrin wa kọ́.
Ní ìpínlẹ̀ Chiapas àti Oaxaca ní Mexico, àwọn arákùnrin àti arábìnrin ọgọ́rùn mẹ́fà àti àádọ́ta lé ní márùn-ún [655] ni kò nílé lórí mọ́ lẹ́yìn tí ìjì líle kan wáyé ní September 7. Ohun tí wọ́n gbèrò láti ṣe ni pé kí wọ́n tún ilé ọgọ́rùn mẹ́ta àti mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [315] kọ́, wọ́n sì máa tún Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] kọ́. Yàtọ̀ sáwọn yẹn, àwọn ilé tó bàjẹ́ tí wọ́n fẹ́ tún ṣe tó ẹgbẹ̀rún kan àti mọ́kàndínlógójì [1,039], Gbọ̀ngàn Ìjọba tó tó ọgọ́rùn kan ó lé mẹ́jọ [108] àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ mẹ́ta.
Ní Mexico City àti ní Morelos àti Puebla, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ọgọ́rùn mẹ́rin ó lé ọgọ́ta àti mẹ́ta [463] ni ìjì líle tó wáyé ní September 19 ba ilé wọn jẹ́. Ilé tó tó méjìdínlọ́gọ́jọ [158] ni wọ́n máa tún kọ́, wọ́n tún máa tún ilé ọgọ́rùn mẹ́fà [600] ṣe, wọ́n á sì tún ṣàtúnṣe sí Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́kàndínlógójì [39] àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan.
Ìjì líle tó wáyé ní September 7 ní Guatemala sọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin mẹ́rìndínlógójì [36] di aláìnílé lórí. Láàárín oṣù díẹ̀ sí i, àwọn ìránṣẹ́ ìkọ́lé àti àwọn arákùnrin tó wà ládùúgbò máa tún ilé mẹ́sàn-án àti Gbọ̀ngàn Ìjọba kan kọ́. Wọ́n máa tún ilé ogún [20] kọ́, wọ́n sì máa tún Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rin kọ́.
Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ pé àwọn ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ mọ́kàndínlógójì [39] ló máa bójú tó iṣẹ́ yìí, ó máa ná wọn tó mílíọ̀nù mẹ́wàá owó dọ́là [$10 million] iṣẹ́ náà sì máa gbà tó oṣù márùn-un sí mẹ́fà. Àwọn ìránṣẹ́ ìkọ́lé ọgbọ̀n [30] ló ti ń gbara di láti lọ sí àwọn ibi tí àjálù yẹn ti wáyé, àwọn ará tó tó ẹgbẹ̀rún kan ó dín ọgbọ̀n [970] ló sì ti yọ̀ǹda ara wọn láti lọ́wọ́ sí iṣẹ́ àtúnṣe yìí. Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún iṣẹ́ yìí àtàwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ní ìpín nínú ètò ìrànwọ́ tá a ṣe fáwọn ará wa tí àjálù yìí dé bá.—2 Kọ́ríńtì 8:4.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000
Guatemala: Juan Carlos Rodas +502-5967-6015
Mexico: Gamaliel Camarillo, +52-555-133-3048