Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn jàǹdùkú Huichol ló fọ́ ilé yìí, wọ́n jí ilẹ̀kùn, wíńdò, àti òrùlé. Fọ́tò kékeré: Àwọn ará Ìjọ Huichol tí wọ́n lé kúrò nílé.

FEBRUARY 6, 2018
MEXICO

Wọ́n Fi Ipá Lé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó Jẹ́ Huichol Kúrò Nílé Wọn ní Jalisco, Orílẹ̀-Èdè Mexico

Wọ́n Fi Ipá Lé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó Jẹ́ Huichol Kúrò Nílé Wọn ní Jalisco, Orílẹ̀-Èdè Mexico

MEXICO CITY​—Ní December 4, 2017, àwọn kan kóra jọ ní àdúgbò Tuxpan de Bolaños, tó wà nítòsí àwọn àpáta ní Jalisco, Mexico, wọ́n sì lé àwọn ará wa méjìlá [12] tí wọ́n jẹ́ ọmọ Huichol kúrò nílé, papọ̀ pẹ̀lú àwọn mẹ́rìndínlógójì [36] míì tó máa ń wá sí ìpàdé. Àwọn èèyàn yẹn ń bínú pé àwọn ará wa ò bá àwọn lọ́wọ́ sí àwọn àṣà ẹ̀sìn tí àwọn Huichol máa ń ṣe. Torí ohun tí wọ́n ṣe yìí, àwọn ará wa ti lọ bá àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n ran àwọn lọ́wọ́.

Wọ́n jí ẹrù àwọn ará wa kó, wọ́n sì ju àwọn míì síta.

Ìjọba Mexico ò kóyán àwọn àṣà Huichol kéré rárá, torí náà, dé ìwọ̀n àyè kan, ìjọba fún wọn lómìnira láti ṣe bó ṣe wù wọ́n. Ṣe làwọn tó ń rí sí àṣà àwọn Huichol ni káwọn èèyàn wá lé àwọn ará wa kúrò nílé wọn, wọ́n tún jà wọ́n lólè, wọ́n yọ ilẹ̀kùn wọn lọ, wíńdò àti òrùlé wọn. Wọ́n tún da àwọn ẹrù wọn míì sínú omi. Lẹ́yìn náà, wọ́n mú àwọn ará wa lọ sínú igbó kan, wọ́n sì sọ pé àwọn máa pa wọ́n tí wọ́n bá pa dà wálé.

Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Huichol níwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Aṣojú kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Mexico rìnrìn àjò láti lọ bá àwọn tí wọ́n lé kúrò nílé, kí wọ́n lè fi Bíbélì ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n sì bá wọn ṣètò ilé tí wọ́n lè forí pamọ́ sí. Àwọn tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹjọ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lọ rí àwọn aláṣẹ ìlú Jalisco, ẹni tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, agbẹjọ́rò fún ìjọba lágbègbè yẹn, àti ẹni tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn tá a hùwà ìkà sí. Àwọn yìí ti ń ṣe ìwádìí lórí ohun tí wọ́n ṣe sáwọn ará wa yìí.

Arákùnrin Gamaliel Camarillo, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mexico sọ pé: “Ó dùn wá gan-an pé wọ́n ń gbéjà ko àwọn ará wa tó jẹ ẹni àlàáfíà tó sì ń bọ̀wọ̀ fún àṣà àwọn míì, torí pé wọn ò bá wọn lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ẹ̀sìn tí kò bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu. A gbà pé àwọn aláṣẹ máa ṣe nǹkan sí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń ṣe inúnibíni sáwọn ará wa nítorí ẹ̀sìn.”

À ń gbàdúrà fún àwọn ará wa tó ti pàdánù ilé àtàwọn nǹkan ìní wọn, ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa lo ètò rẹ̀ láti pèsè ìrànlọ́wọ́ táwọn ará wa nílò.​—Aísáyà 32:2.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Mexico: Gamaliel Camarillo, +52-555-133-3048