Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 28, 2019
MOZAMBIQUE

Ìjì Líle Kenneth Jà ní Àríwá Mòsáńbíìkì

Ìjì Líle Kenneth Jà ní Àríwá Mòsáńbíìkì

Ní April 25, 2019, ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Kenneth jà ní àríwá orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì. Ìgbà kejì nìyí tí ìjì líle tún jà léyìn Ìjì Líle Idai tó jà lóṣù March lórílẹ̀-èdè náà. Ìjì tó jà kẹ́yìn yìí fa omíyalé tó pọ̀, ó ba ọ̀pọ̀ ilé àti ọ̀nà jẹ́, kódà ńṣe ló mú kí nǹkan túbọ̀ nira lágbègbè tó ti jà.

Nǹkan bíi ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) akéde ló ń gbé ní agbègbè Cabo Delgado, àmọ́ kò sí ìkankan lára wọn tí ìjì líle náà ṣe lẹ́se tàbí tó pa. Síbẹ̀, ìjì náà ba mẹ́sàn-án lára ilé àwọn ará wa jẹ́ kọjá àtúnṣe, ó sì tún ba ilé mẹ́rìndínlógún (16) míì jẹ́ díẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó ba Gbọ̀ngàn Ìjọba kan jẹ́ pátápátá, ó sì tún ba mẹ́ta míì jẹ́ díẹ̀. Alábòójútó àyíká tó wà lágbègbè náà àti aṣojú kan láti Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ pẹ̀lú arákùnrin méjì láti ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè lọ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn ìjọ tí àjálù náà kàn, wọ́n sì fún wọn ní ìṣírí.

À ń rántí àwọn ará wa yìí nínú àdúrà bí wọ́n ṣe ń wojú Jèhófà, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé e pé kó fún wọn lókun, kó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ “ní àkókò wàhálà.”—Sáàmù 46:1.