Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 17, 2020
MOZAMBIQUE

A Mú Ìwé Ìhìn Rere Mátíù Jáde Lédè Gitonga àti Ronga

A Mú Ìwé Ìhìn Rere Mátíù Jáde Lédè Gitonga àti Ronga

Ní November 14 àti 15, 2020, a mú Ìwé Ìhìn Rere Mátíù (The Bible​—The Gospel According to Matthew) jáde lórí ẹ̀rọ láwọn èdè méjì tí wọ́n ń sọ lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Mozambique, ìyẹn èdè Gitonga àti Ronga. Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìwé yìí jẹ́ fáwọn akéde ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mẹ́rìnlélógún (524) tó ń sọ èdè Gitonga àtàwọn akéde ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mọ́kànlá (1,911) tó ń sọ èdè Ronga, ẹ̀bùn yìí sì bọ́ sákòókò gan-an.

Arákùnrin Amaro Teixeira, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Orílẹ̀-Èdè Mozambique ló mú ìwé Bíbélì yìí jáde nínú àsọyé tá a ti gbà sílẹ̀, àwọn ará sì wo fídíò náà nínú ilé wọn. Bákan náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká gbé ètò yìí sáfẹ́fẹ́ lórí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò. Wọ́n tún máa tẹ ìwé yìí sí ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé mẹ́rìnlélọ́gọ́ta (64), torí ọ̀pọ̀ ni ò ní fóònù tí wọ́n lè fi ka torí ẹ̀rọ.

Arákùnrin Teixeira sọ pé: “Wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde láwọn èdè yìí. Inú wa dùn gan-an láti ní ìwé Ìhìn Rere Mátíù, torí ó sọ̀rọ̀ nípa ìlà ìdílé Jésù, bí wọ́n ṣe bí i, ìwàásù tó ṣe lórí òkè àtàwọn nǹkan tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”

Nígbà tí atúmọ̀ èdè kan ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa rí lára àwọn ará tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì tí wọ́n tú lọ́nà tó péye, tó sì rọrùn lóye yìí, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ló wà nínú ìwé Ìhìn Rere Mátíù. Mo kàn ń ro bí omijé ayọ̀ á ṣe máa bọ́ lójú àwọn ará tí wọ́n bá ń ka ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè lédè abínibí wọn.”

Àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mẹ́rìnlélógún (224,000) èèyàn ló ń sọ èdè Gitonga, wọ́n sì sọ pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́tàlélógún (423,000) ló ń sọ èdè Ronga. Àdúrà wa ni pé kí Bíbélì yìí ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti rí ‘ọ̀nà tó lọ sí ìyè.’​—Mátíù 7:14.