Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Sai Asher ń sọ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi

APRIL 21, 2021
MYANMAR

Ìrántí Ikú Kristi Ọdún 2021​—Myanmar

Wọ́n Ṣe Ìrántí Ikú Kristi Látorí Fóònù Láìka Rògbòdìyàn Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Sí

Ìrántí Ikú Kristi Ọdún 2021​—Myanmar

Láti February 2021 ni rògbòdìyàn ti ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Myanmar. Ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, ìjà ńlá bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ibi lórílẹ̀-èdè náà. Látàrí èyí, ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọgọ́rùn-ún kan ó lé méjì (5,102 ) ni wọn ò rí Íńtánẹ́ẹ̀tì lò. Torí náà, wọ́n lo fóònù láti gbọ́ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi.

Ní ìlú kan, àwọn èèyàn ń bára wọn jà, wọ́n sì ń yìnbọn lọ́tùn-ún lósì lọ́jọ́ Ìrántí Ikú Kristi. Àwọn sójà bẹ̀rẹ̀ sí í ya ilé kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì ń wá àwọn tó ń fi ẹ̀hónú hàn. Ọ̀rọ̀ tó wà ní Àìsáyà 30:15 tó jẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2021 tó sọ pé, ‘ẹ fara balẹ̀, kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà’ tu àwọn ará wa nínú gan-an. Inú ilé wọn ni wọ́n wà, wọn ò jẹ́ kí ohùn wọn lọ sókè jù, wọ́n paná, wọ́n sì gbádùn Ìrántí Ikú Kristi náà láìsí wàhálà kankan. Láìka gbogbo rògbòdìyàn náà sí, àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yẹn pọ̀ ju tàtẹ̀yìnwá lọ. Ọ̀pọ̀ ló tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látorí fóònù.

Ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà, àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mẹ́tàdínlọ́gọrin (11,877), ìyẹn sì fi ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ (1,440) ju iye àwọn tó wá lọ́dún 2019.

Arábìnrin méjì ń lo íńtánẹ́ẹ̀tì láti wo àsọyé Ìrántí Ikú Kristi lórí fóònù wọn. Wọ́n sì lo ẹ̀rọ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ kó lè ṣeé ṣe fáwọn míì láti tẹ́tí sí i láti ibi tí wọ́n wà

Ó dá wa lójú pé inú Jèhófà Baba wa ọ̀run ń dùn bó ṣe ń rí i tí àwọn ará wa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa jọ́sìn ẹ̀ láìka rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ sí.​—Òwe 27:11.