Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

APRIL 5, 2019
NÀÌJÍRÍÀ

“Ìdùnnú Ṣubú Layọ̀”—A mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Jáde Lédè Méjì ní Nàìjíríà

“Ìdùnnú Ṣubú Layọ̀”—A mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Jáde Lédè Méjì ní Nàìjíríà

Ní January 12, 2019, àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe àkànṣe ìpàdé kan ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní ìlú Benin. Nínú ìpàdé náà, Arákùnrin Geoffrey Jackson, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí kéde pé a ti mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde ní èdè Isoko àti Yorùbá. Àwọn tó wà níbi ìpàdé náà àtàwọn tó wò ó láwọn ibi tá a ta àtagbà rẹ̀ sí jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti méjìléláàádọ́rin (60,672). A ta àtagbà ìpàdé náà sí Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rìndínláàádọ́fà (106) àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ mẹ́sàn-án ní Nàìjíríà àti láwọn ibì mélòó kan lórílẹ̀-èdè Benin.

Arákùnrin Jackson àti ìdílé kan ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní ìlú Benin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Arákùnrin Gad Edia tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Nàìjíríà sọ pé: “Ọdún mẹ́ta àti oṣù méjì ni wọ́n fi túmọ̀ Bíbélì yìí sí èdè Isoko, ó sì gba ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́ta kí wọ́n tó parí rẹ̀ lédè Yorùbá.” Ó wá sọ pé: “Ní Nàìjíríà, ó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) àwọn ará tó ń sọ èdè Isoko, àwọn tó ń sọ èdè Yorùbá tí wọ́n sì ń kà á lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000). Nígbà táwọn ará gba Bíbélì tá a tún ṣe yìí, ẹnì kan sọ bó ṣe rí lára àwọn tó wà níbẹ̀ pé ‘ìdùnnú ṣubú layọ̀.’ Torí náà, a lè fi gbogbo ẹnu sọ pé ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ!”

Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lódindi tàbí lápá kan ní èdè mọ́kàndínlọ́gọ́sàn-án (179).

A dúpẹ́ pé ní báyìí, àwọn ará wa lè ka Bíbélì láwọn èdè yìí, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́nà tó túbọ̀ rọrùn.—2 Tímótì 3:17.