Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 27, 2019
NÀÌJÍRÍÀ

A Mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun Jáde Lédè Tiv

A Mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun Jáde Lédè Tiv

Ní December 20, 2019, Arákùnrin Wilfred Simmons, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà, mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Tiv. Ìfilọ̀ náà wáyé ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! tá a ṣe ní gbọ̀ngàn tó ń jẹ́ City Bay Event Center ní Makurdi, Ìpínlẹ̀ Benue, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ó tó ọdún méjì tí wọ́n fi túmọ̀ Bíbélì náà, àmọ́ àkókò tó jáde sí yìí dáa gan-an ni. Ọ̀kan lára èdè pàtàkì tí wọ́n ń sọ ní Nàìjíríà ni èdè Tiv, àwọn tó ń sọ èdè náà sì lé ní mílíọ̀nù márùn-ún. Àwọn akéde tó ń sọ èdè Tiv ti pọ̀ sí i lẹ́nu àìpẹ́ yìí, láti ẹgbẹ̀ta (600) ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, wọ́n ti di ẹgbẹ̀rún kan ó lé méjìlá (1,012) báyìí.

Ó dá wa lójú pé Bíbélì tuntun yìí máa fi kún ìbísí tó ń wáyé láàárín àwọn tó ń sọ èdè Tiv nínú pápá ‘funfun, tó sì ti tó kórè’ báyìí.​—Jòhánù 4:35.