OCTOBER 23, 2018
NÀÌJÍRÍÀ
Òjò Àrọ̀ọ̀rọ̀dá Fa Omíyalé ní Nàìjíríà
Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá ti fa omíyalé lọ́pọ̀ ibi ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti láwọn agbègbè tó wà ní gúúsù. Odò Benue àti odò Niger, àwọn odò méjèèjì tó la orílẹ̀-èdè náà já ti kún kọjá ààlà wọn, èyí ti lé ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò níbi tí wọ́n ń gbé, ó sì lé ní ọgọ́rùn-ún (100) èèyàn tó pa.
Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ sọ pé kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó bá àjálù náà lọ tàbí tó fara pa. Àmọ́, ó kéré tán, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) akéde ni omíyalé náà lé kúrò níbi tí wọ́n ń gbé, ó sì ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lára wọn tó nílò ìrànlọ́wọ́. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó sá kúrò nílé wọn yìí ló ti ń gbé lọ́dọ̀ àwọn ará láwọn agbègbè tí àjálù náà ò dé.
A ti ní kí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti pèsè àwọn nǹkan tí àwọn ará nílò, kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí nípa tẹ̀mí. Méjì lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Nàìjíríà àti alábòójútó àyíká kan pẹ̀lú àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn àti Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn akéde tó wà láwọn agbègbè tọ́rọ̀ kàn, láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àjálù yìí ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro, Baba wa ọ̀run, Jèhófà, ṣì ‘ni odi ààbò wa ní àkókò wàhálà.—Sáàmù 37:39.