AUGUST 10, 2016
NAGORNO-KARABAKH
Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh Rán Ẹni tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kó Ṣiṣẹ́ Ológun Lọ Sẹ́wọ̀n Láìtọ́
Artur Avanesyan tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún ń ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjì ààbọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Shushi, lórílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh. Bẹ́ẹ̀, ọ̀dọ́kùnrin yìí sọ pé òun ṣe tán láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun. Gbogbo oríṣi ilé ẹjọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh ló ti gbọ́ ẹjọ́ ọ̀dọ́kùnrin yìí, àmọ́ wọn ò gbà pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti kọṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan. Ó ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́, tó sì dá a lójú, ó ní: “Ẹ̀rí ọkàn mi ò gbà mí láyè láti ṣiṣẹ́ ológun. Mo nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò mi, mi ò sì fẹ́ gbé ohun ìjà tàbí kí n tiẹ̀ kọ́ bí màá ṣe fi pààyàn.” Ó tún sọ pé: “Kì í ṣe pé mò ń sá fún ohun tó yẹ kí ń ṣe fún orílẹ̀-èdè mi. Mo ní kí ìjọba jẹ́ kí n ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun, àmọ́ wọn ò gbà fún mi.”
Ó Fẹ́ Ṣiṣẹ́ Àṣesìnlú, àmọ́ Ìjọba Ò Gbà
Ní January 29, 2014, ìjọba ní kí Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan fojú ba ẹ̀ka iṣẹ́ ológun nílùú Askeran, ìyẹn Askeran City Military Commissariat lórílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh. Nígbà tó di ọjọ́ kejì, ó kọ̀wé sí ìjọba láti ṣàlàyé fún wọn pé ẹ̀rí ọkàn òun ò ní jẹ́ kóun lè ṣiṣẹ́ ológun, àmọ́ ó sọ pé òun ṣe tán àtiṣe iṣẹ́ àṣesìnlú. Torí ó mọ̀ pé kò sí ìṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú ní orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh, ó fi ọ̀rọ̀ yìí tó agbẹjọ́rò kan létí.
Torí pé Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan ní ìwé àṣẹ láti gbé ní orílẹ̀-èdè Àméníà, agbẹjọ́rò rẹ̀ kàn sí àwọn aláṣẹ lórílẹ̀-èdè Àméníà àti Nagorno-Karabakh, ó sì jọ pé orílẹ̀-èdè Àméníà máa fọwọ́ sí i pé kí Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan wá ṣiṣẹ́ àṣesìnlú níbẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan wá kó lọ sí Àméníà, nírètí pé ọ̀rọ̀ náà máa bọ́ sí i. Ní February 13, 2014, ó kọ̀wé sí ẹ̀ka iṣẹ́ ológun tó ń jẹ́ Masis Military Commissariat lórílẹ̀-èdè Àméníà.
Àmọ́ àjọ tó ń rí sí iṣẹ́ àṣesìnlú lórílẹ̀-èdè Àméníà ò pe Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan títí. Bó ṣe di July 14, 2014, àwọn ọlọ́pàá ìlú Yerevan, lórílẹ̀-èdè Àméníà ní kó fojú ba àgọ́ ọlọ́pàá. Àṣé àwọn ọlọ́pàá láti orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh ti ń dúró dè é níbẹ̀. Ṣe ni àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Àméníà fẹ́ fà á lé ìjọba orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh lọ́wọ́. Nígbà tó dé, kíá ni wọ́n mú un, wọ́n sì fipá mú un kúrò nílùú Yerevan pa dà sílùú Askeran ní Nagorno-Karabakh, láì fojú ba ilé ẹjọ́ tàbí kí wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìlànà míì tó yẹ.
Wọ́n Fi sí Àtìmọ́lé, Wọ́n Wá Gbọ́ Ẹjọ́ Rẹ̀
Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] péré ni Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan nígbà yẹn, July 14, 2014 tí wọ́n mú un yìí sì ni ọjọ́ àkọ́kọ́ tó máa lò lẹ́wọ̀n. Lọ́jọ́ kejì, wọ́n mú un láti ẹ̀wọ̀n lọ sí ilé ẹjọ́ tó máa ń kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ tí ọ̀rọ̀ kan bá wáyé lórílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh. Ibẹ̀ ló ti mò pé ilé ẹjọ́ yìí ti ní kí àwọn agbófinró wá mú òun tẹ́lẹ̀, kí wọ́n sì ti òun mọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ òun. Ilé ẹjọ́ náà ṣì gùn lé ohun tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n sì rán Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan lọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Shushi. Ó gbìyànjú títí kí wọ́n má bàa fi sí àtìmọ́lé láìtíì dúró rojọ́, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí.
Ní September 30, 2014, Spartak Grigoryan tó jẹ́ adájọ́ ní ilé ẹjọ́ tó máa ń kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ ní Nagorno-Karabakh rán Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì àtààbọ̀ torí pé o kọ iṣẹ́ ológun. * Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, àmọ́ Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn àti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh fagi lé e, wọ́n ní ó gbọ́dọ̀ ṣẹ̀wọ̀n. Ó wá já sí pé, ó máa wà lẹ́wọ̀n títí di January 2017.
Bí Wọ́n Tiẹ̀ Fi Sẹ́wọ̀n Láìtọ́, Kò Kúrò Lórí Ìpinnu Rẹ̀
Ọ̀gbẹ́ni Shane Brady, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ sọ pé: “Torí ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan gbà gbọ́ ni wọ́n ṣe mú un, tí wọ́n tì í mọ́lé, tí wọ́n fẹ̀sùn kàn án, tí wọ́n sì dá a lẹ́bi. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rán an lọ sẹ́wọ̀n láìtọ́, ó ṣì dúró lórí ìpinnu ẹ̀, kò ṣe ohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn ẹ̀.” Ọ̀gbẹ́ni Brady jábọ̀ pé àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n ti gba Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan láyè báyìí pé kó ní Bíbélì àtàwọn ìwé tó lè máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀, wọ́n sì gba àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ láyè láti máa wá bẹ̀ ẹ́ wò.
Ọ̀gbẹ́ni Avanesyan ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ ibi pẹlẹbẹ lọ̀bẹ ń fi lélẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè náà. Ló bá kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn ilé ẹjọ́ ECHR). Ó retí pé kí wọ́n gbèjà òun, torí léraléra ni ilé ẹjọ́ yìí ti dá àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun láre. Bí àpẹẹrẹ, nínú ẹjọ́ Ọ̀gbẹ́ni Bayatyan, ìyẹn Bayatyan v. Àméníà, Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní ilé ẹjọ́ ECHR dájọ́ pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò bá jẹ́ kó ṣe é torí pé gbogbo èèyàn ló ní òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn. Ìdájọ́ yìí kan náà ni wọ́n si ń ṣe lórí irú àwọn ẹjọ́ yìí. * Àmọ́, ó lè jẹ́ pé oṣù mélòó kan lẹ́yìn tí ọ̀gbẹ́ni Avanesyan bá ṣẹ̀wọ̀n tán ni èsì ilé ẹjọ́ ECHR ṣẹ̀ṣẹ̀ máa dé.
Ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR ń dá lórí irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí ti mú kí ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè kan bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe é, kódà lásìkò tí nǹkan ò rọrùn níbẹ̀ tàbí nígbà ogun pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, ní June 2015, ilé ẹjọ́ gíga kan lórílẹ̀-èdè Ukraine dájọ́ pé nígbà tí ìjọba bá ń kó àwọn èèyan wọṣẹ́ ológun, àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú ní tiwọn.
Ṣé Ìrètí Wà Pé Ìjọba Máa Wá Nǹkan Ṣe sí Ọ̀rọ̀ Àwọn tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun ní Orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Nagorno-Karabakh àti gbogbo wọn kárí ayé ń retí pé ìjọba máa fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun ní Nagorno-Karabakh torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe é. Wọ́n retí pé kí ìjọba gba àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jẹ́ èèyàn àlàáfíà yìí láyè láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò kí wọ́n rán wọn lọ sẹ́wọ̀n. Tí ìjọba bá fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun ní Nagorno-Karabakh torí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn, a jẹ́ pé wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà tí ìjọba fi lélẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù nìyẹn, ìyẹn á sì fi hàn pé wọ́n gbà pé àwọn ọ̀dọ́kùnrin bíi Artur Avanesyan lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́.
^ ìpínrọ̀ 10 Àtìgbà tí wọ́n ti tì í mọ́lé ní July 14, 2014 ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọdún méjì àtààbọ̀ yìí fún un.
^ ìpínrọ̀ 13 Wo ẹjọ́ Erçep v. Turkey, no. 43965/04, 22 November 2011; ẹjọ́ Feti Demirtaş v. Turkey, no. 5260/07, 17 January 2012; ẹjọ́ Buldu and Others v. Turkey, no. 14017/08, 3 June 2014.