Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Nàmíbíà
Àtọdún 1929 ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ẹ̀sìn wọn ní orílẹ̀-èdè Nàmíbíà. Àmọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè South Africa tí àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè pàṣẹ pé kó máa jọba lórí Nàmíbíà fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láti nǹkan bí ọdún 1950 sí 1954 títí di nǹkan bí ọdún 1975 sí 1979, àwọn aláṣẹ ò jẹ́ kí àwọn aláwọ̀ funfun dé ibi táwọn èèyàn dúdú wà láìjẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ gbàwé àṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba, ìyẹn ló jẹ́ kó nira fáwọn míṣọ́nnárì tó wá láti orílẹ̀-èdè míì láti ṣiṣẹ́ wọn. Láwọn ọdún yẹn, àwọn aṣáájú ìsìn àtàwọn aláṣẹ ìlú fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí màbo torí pé wọ́n ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì.
Ní March 21, 1990, orílẹ̀-èdè Nàmíbíà gbòmìnira kúrò lábẹ́ South Africa. Wọ́n ti wá ṣòfin tiwọn, èyí sì mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túbọ̀ lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Lọ́dún 2008, wọ́n forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Nàmíbíà dùn pé àwọn ti lè máa ṣe ohun táwọn gbà gbọ́ ní fàlàlà báyìí.