Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 25, 2017
NEPAL

Àkúnya Omi àti Ilẹ̀ Yíya Ba Orílẹ̀-èdè Nepal Jẹ́

Àkúnya Omi àti Ilẹ̀ Yíya Ba Orílẹ̀-èdè Nepal Jẹ́

Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá kan rọ̀ lórílẹ̀-èdè Nepal, ó sì fa àkúnya omi àti ilẹ̀ yíya. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn di aláìnílé, ó sì pa àwọn èèyàn tó lé ní ogóje [140]. Àkúnya omi náà ba àwọn ojú títì jẹ́, ó sì ba iná mànàmáná jẹ́, èyí wá mú kó nira láti ran àwọn tọ́rọ̀ kàn lọ́wọ́.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Japan náà ló ń bójú tó iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Nepal, wọ́n sì sọ pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó fara pa tàbí tó kú nínú jàǹbá náà. Àmọ́, ó di dandan fún ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin láti filé wọn sílẹ̀, torí pé àkúnya omi tí bá àwọn ilé ọ̀hún jẹ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè náà ti ń ran àwọn ará bíi tiwọn lọ́wọ́, ìyẹn àwọn tómi gbalé wọn.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Japan: Ichiki Matsunaga, +81-46-233-0005

Nepal: Reuben Thapaliya, +977-9813469616