AUGUST 8, 2019
NETHERLANDS
Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—Utrecht, Netherlands
Déètì: August 2 sí 4, 2019
Ibi Tá A Ti Ṣe É: Jaarbeurs Hallencomple, ìlú Utrecht, orílẹ̀-èdè Netherlands
Èdè: Lárúbáwá, Dutch, Èdè Àwọn Adití lọ́nà ti ilẹ̀ Jámánì, Gẹ̀ẹ́sì, Papiamento, Polish, Potogí, Sípáníìṣì, Twi
Àwọn Tó Wá: Ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùn-ún dín lógójì (42,335)
Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: Ọgọ́rùn-ún méjì àti méjìlá (212)
Àwọn Tó Wá Láti Ilẹ̀ Òkèèrè: Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000)
Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíísì Tá A Pè: Australasia, Belgium, Brazil, Kánádà, Kòlóńbíà, Indonesia, Kòríà, Pọ́túgà, Ròmáníà, South Africa, Suriname, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
Ìrírí: Alábòójútó ilé-iṣẹ́ tí Jaarbeurs Hallencomplex gbé iṣẹ́ ìmọ́tótó ọgbà náà fún pe arákùnrin wa tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ lórí fóònù, ó ní: “Àwọn kan wà níbí tó ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tó yẹ ká ṣe láìjáfara, wọ́n ń tún àyíká ṣe, wọ́n sì tún ṣètò bí gbogbo nǹkan ṣe máa wà ní mímọ́ tónítóní. Mo gbà pé wọ́n á fẹ́ẹ̀ fi ibí sílẹ̀ lọ́nà tó dáa ju bí wọ́n ṣe gbà á lọ́wọ́ wa lọ. Mí ò rírú èyí rí, ó jọ mi lójú gan-an ni! Kódà, wọ́n tún àwọn ibì kan nínú ilé oúnjẹ tá ò lò báyìí ṣe! Èèyàn méjì ló máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó níbi ilé ìtura, bí ohunkóhun bá sì ṣẹlẹ̀, kíá, wọ́n ti ṣàtúnṣe ẹ̀. Kò ṣẹlẹ̀ rí!”
Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń kí àwọn tó wá káàbọ̀ ní pápákọ̀ òfuurufú
Àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì ń kí àwọn ará tó wá láti orílẹ̀-èdè míì káàbọ̀ nígbà tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Netherlands
Ọ̀kan lára àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú arábìnrin kan láti fi ìwé pé àwọn èèyàn wá sí àpéjọ náà
Àwọn ará ń gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà nínú gbọ̀ngàn Jaarbeurs Hallencomplex. Ibi márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ṣe àtagbà ètò náà sí
Lára àwọn ọgọ́rùn-ún méjì àti méjìlá (212) arákùnrin àti arábìnrin tó ṣèrìbọmi
Àwọn ará ń tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n sì ń ṣàkọsílẹ̀ bí ìpàdé náà ṣe ń lọ
Àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì ń fún ara wọn lẹ́bùn
Arákùnrin Geoffrey Jackson tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń sọ àsọyé tó kẹ́yìn lọ́jọ́ Sunday
Àwọn Míṣọ́nnárì àti àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún ń juwọ́ sí gbogbo àwọn tó wá sí àpéjọ náà nígbà tó parí