DECEMBER 9, 2016
NEW CALEDONIA
Omi àti Yẹ̀pẹ̀ Ya ní New Caledonia
Ní November 21, òjò ńlá kan bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ ní ìlà oòrùn etí òkun lórílẹ̀-èdè New Caledonia, ìròyìn tá a sì gbọ́ ni pé láàárín wákàtí méjìlá [12], omi òjò tó rọ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó ẹsẹ̀ bàtà méjì. Ìgbà àkọ́kọ́ tí òjò máa le tó báyìí lágbègbè náà nìyí. Òjò yẹn mú kí omi yalé àwọn èèyàn, ó sì mú kí yẹ̀pẹ̀ ya. Èèyàn márùn-ún ló kú torí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, wọ́n ṣì ń wá èèyàn mẹ́ta, àwọn mẹ́fà ló sì fara pa.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni méjì nínú àwọn márùn-ún tí wọ́n rí òkú wọn. Wọ́n ní ọmọ méjì tó ti dàgbà, àwọn ọmọ méjèèjì sì wà lára àwọn tí wọ́n ṣì ń wá.
Lọ́jọ́ kejì tí àjálù yẹn ṣẹlẹ̀, aṣojú méjì láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè New Caledonia dé sí àgbègbè yẹn kí wọ́n lè fún àwọn tí àjálù náà pa lára ní ohun tí wọ́n nílò, kí wọ́n sì fi Bíbélì tù wọ́n nínú. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ogójì [40] tí wọ́n wà lágbègbè yẹn yọ̀ǹda láti bá àwọn ará wọn tún ilé wọn ṣe, ìyẹn àwọn tí omi ya ilé wọn.
Láti oríléeṣẹ́ wa ní New York ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò bá a ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá, wọ́n ń lo owó táwọn èèyàn fi ń ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000
New Caledonia: Jean-Pierre Francine, +687-43-75-00