NOVEMBER 18, 2019
NORTH MACEDONIA
Wọ́n “Sọdá Wá sí Makedóníà” fún Àkànṣe Ìwàásù
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní North Makedóníà ṣètò àkànṣe ìwàásù ní August 1 sí October 31, 2019, kí wọ́n lè wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè Makedóníà àti èdè Alibéníà ní ìpínlẹ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn.
Ní North Makedóníà, àwọn tó ń sọ èdè Makedóníà ju mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (1,300,000) lọ, àwọn tó sì ń sọ èdè Alibéníà ju ìdajì mílíọ̀nù kan lọ. Àmọ́, nínú àwọn akéde ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (1,300) tó ń sọ èdè Makedóníà lórílẹ̀-èdè yẹn, ẹgbẹ̀rún kan péré ló wà ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Makedóníà, ogún (20) akéde péré ló sì wà ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Alibéníà. Torí náà, àwọn akéde ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (476) ló wá ṣèrànwọ́ fáwọn akéde yìí láti àwọn orílẹ̀-èdè méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè náà ni Alibéníà, Austria, Belgium, Jámánì, Ítálì, Sweden àti Switzerland.
Nígbà àkànṣe ìwàásù yẹn, arákùnrin kan pàdé ọkùnrin kan tó ń da ewúrẹ́ lójú ọ̀nà. Bí ọkùnrin tó ń da ewúrẹ́ náà ṣe rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun ń bá sọ̀rọ̀, kíá ló yọ ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni jáde nínú àpò rẹ̀, ó sọ pé ìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí wá wàásù láti Ítálì ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni wọ́n fún òun ní ìwé náà. Ó tiẹ̀ sọ pé ojoojúmọ́ lòun ń ka ìwé náà, kódà òun ti há àwọn àkòrí kan sórí nínú ẹ̀. Báwọn ará ṣe ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò nìyẹn.
Báwọn ará tó ń sọ èdè Makedóníà àti Alibéníà ṣe tú yáyá tù yàyà láti ti àkànṣe ìwàásù yìí lẹ́yìn rán wa létí bí Pọ́ọ̀lù náà ṣe múra tán láti “sọdá wá sí Makedóníà.”—Ìṣe 16:9.