Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 19, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019​—Houston, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (Gẹ̀ẹ́sì)

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019​—Houston, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (Gẹ̀ẹ́sì)
  • Déètì: July 12-14, 2019

  • Ibi Tá A Ti Ṣe É: Pápá Ìṣeré NRG ní Houston, ìpínlẹ̀ Texas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

  • Èdè: Gẹ̀ẹ́sì àti Korean

  • Àwọn Tó Wá: 50,901

  • Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 401

  • Àwọn Tó Wá Láti Ilẹ̀ Òkèèrè: 5,000

  • Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá A Pè: Australasia, Belgium, Brazil, Britain, Kánádà, Kòlóńbíà, Czech-Slovak, Faransé, Íńdíà, Ítálì, Japan, Kòríà, Philippines àti Scandinavia

  • Ìrírí: Inú Sylvester Turner tó jẹ́ olórí ìlú Houston dùn láti rí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000) àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn àlejò tó wá sí ìlú Houston fún àpéjọ náà. Ó sọ pé: “A ò lè sọ bí inú wa ṣe dùn tó torí ńṣe lara tù wa pẹ̀sẹ̀. Ìdí nìyẹn tí a fi gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀. Tẹ́yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá lè máa wá lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún, tayọ̀tayọ̀ là á máa kí i yín káààbọ̀ sí ilú Houston. Àá ma retí yín lọ́dún tó ń bọ̀ àtèyí tó tẹ̀ lé e.”

 

Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń kí àwọn àlejò káàbọ̀ sí Houston

Àwọn àlejò tó wá ń wàásù pẹ̀lú àwọn ará tó ń gbé lágbègbè náà

Díẹ̀ lára ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ẹyọ kan (401) àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó ṣe ìrìbọmi

Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ń sọ àsọyé tó kẹ́yìn lọ́jọ́ Saturday

Àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì, tí díẹ̀ lára wọn wọ aṣọ ìbílẹ̀ wọn, fẹ́ ya fọ́tò

Inú àwọn tó wá fún àpéjọ náà ń dùn ṣìnkìn

Àwọn tó péjọ ń pàtẹ́wọ́ fún àwọn tó ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lópin ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Sunday

Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà nílùú náà wà lórí pèpéle nígbà tí wọ́n ń parí àpèjẹ ìrọ̀lẹ́ tí wọ́n ṣe fún àwọn àlejò. Lára àwọn ohun tí wọ́n ṣe nígbà àpéjọ náà ni pé wọ́n kọrin, wọn jó, wọ́n sì sọ̀ ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú Houston