MAY 29, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—Atlanta, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
Déètì: May 17 sí 19, 2019
Ibi Tá A Ti Ṣe É: Pápá Ìṣeré Mercedes-Benz Stadium nílùú Atlanta, ìpínlẹ̀ Georgia, Amẹ́ríkà
Èdè: Amharic, Gẹ̀ẹ́sì, Russian
Àwọn Tó Wá: 46,374
Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 314
Àwọn Tó Wá Láti Ìlẹ̀ Òkèèrè: 5,000
Áwọn Ẹ̀ka Ọ́fíísì Tó Wá: Australasia, Brazil, Britain, Kánádà, Chile, Kòlóńbíà, Etiópíà, Finland, ilẹ̀ Faransé, Gíríìsì, Hong Kong, Israel, Ítálì, Japan, Kazakhstan, Netherlands, Pọ́túgà, Ròmáníà, Scandinavia, Trinidad and Tobago
Èyí ni àkọ́kọ́ lára ìtọ́wò mẹ́rìnlélógún (24) àwọn àpéjọ àgbáyé ọdún 2019 tá a máa gbé sí abala Ìròyìn lórí ìkànnì jw.org/yo bí àpéjọ kọ̀ọ̀kan bá ṣe ń parí.
Àwọn ará ń ya fọ́tò níta ibi tí wọ́n ti ṣe ìpàdé
Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn lọ́jọ́ Sátidé
Àwọn arákùnrin yìí ń ṣe ìrìbọmi fáwọn èèyàn nínú ọ̀kan lára odò méjì tó wà fún ìrìbọmi
Àwọn ará ń fetí sílẹ̀ bí àpéjọ ṣé ń lọ lọ́wọ́
Díẹ̀ lára àwọn mẹ́rìnlélọ́gọ́jọ (164) tó wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè ń juwọ́ sáwọn ará ní pápá ìṣeré Mercedes-Benz Stadium nígbà tí ìpàdé fẹ́ parí lọ́jọ́ Sunday
Àwọn tó wá sí àpéjọ náà bá àwọn ará tó ń gbé lágbègbè yẹn lọ sí òde ẹ̀rí
Àwọn tó wá sí àpéjọ wọ aṣọ ìbílẹ̀, wọ́n sì ń ya fọ́tò
Àwọn ọmọdé gbé àkọlé kan dání tó sọ pé: “Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán; Àá Pàdé ní Párádísè”
Àwọn ará tó wọ aṣọ ìbílẹ̀ Etiópíà lọ́jọ́ tí àpéjọ náà parí
Ní ọ̀kan lára àwọn àpèjẹ tí wọ́n ṣe, àwọn ará ń ṣe eré ìtura, wọ́n sì ń juwọ́ láti fi kí àwọn tó wá síbẹ̀, àkọlé kan wà lẹ́yìn wọ́n tó sọ pé “A Nífẹ̀ẹ́ Yín!”