Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 31, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—Miami, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (Èdè Spanish)

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—Miami, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (Èdè Spanish)
  • Déètì: May 24 sí 26, 2019

  • Ibi Tá A Ti Ṣe É: Marlins Park nílùú Miami, ìpínlẹ̀ Florida, Amẹ́ríkà

  • Èdè: Sípáníìṣì

  • Àwọn Tó Wá: 28,562

  • Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 230

  • Àwọn Tó Wá Láti Ìlẹ̀ Òkèèrè: 4,600

  • Áwọn Ẹ̀ka Ọ́fíísì Tó Wá: Ajẹntínà, Bolivia, Brazil, Britain, Kánádà, Central America, Central Europe, Chile, Kòlóńbíà, Cuba, Ecuador, Paraguay, Peru, Philippines, Sípéènì

 

Àwọn ará tó ń gbé lágbègbè ibi tí wọ́n ti ṣe ìpàdé ń kí àwọn àlejò káàbọ̀ sí Miami

Àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí ń ya fọ́tò níta ibi tí wọ́n ti ṣe ìpàdé

Arákùnrin Kenneth Cook, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn lọ́jọ́ Sátidé

Àwọn mẹ́rin ń ṣe ìrìbọmi

Àwọn tó wá sí àpéjọ náà ń fayọ̀ kọrin pa pọ̀ lọ́jọ́ Sátidé

Arábìnrin kan àti ọ̀kan lára àwọn tó wá sí àpéjọ náà rèé nídìí àtẹ ìwé níta Kislak Center tó wà ní Miami Dade College

Àwọ́n tó ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè dúró sóri pápá ìṣeré nígbà tí àsọyé tó parí lọ́jọ́ Sunday ń lọ lọ́wọ́

Ní ọ̀kan lára àwọn àpèjẹ tí wọ́n ṣe, àwọn arábìnrin yìí ń ṣètò láti pín àwọn oúnjẹ bíi chorizo, empanadas àti paella

Àwọn arábìnrin yìí ń jó ijó ìbílẹ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Sípéèńì níbi àpèjẹ kan tí wọ́n ṣe

Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló pé jọ sí gbọ̀ngàn kan ní West Palm Beach láti gbádùn eré ìtura