Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 12, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—Miami, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (Gẹ̀ẹ́sì)

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—Miami, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (Gẹ̀ẹ́sì)
  • Déètì: July 5 sí 7, 2019

  • Ibi Tá A Ti Ṣeé: Marlins Park ní Miami, Florida, Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

  • Èdè: Gẹ̀ẹ́sì àti Chinese Mandarin

  • Àwọn Tó Wá: 28,000

  • Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 181

  • Àwọn Tó Wá Láti Ilẹ̀ Òkèèrè: 5,000

  • Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá A Pè: Australasia, Brazil, Britain, Kánádà, Kòlóńbíà, Dominican Republic, Fíjì, Gánà, Gírí ìsì, Hong Kong, Israel, Japan, Netherlands, Scandinavia, South Africa, Sípéènì, Taiwan, Trinidad and Tobago, Ukraine

  • Ìrírí: Alákòóso ìlú Miami tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Francis X. Suarez wá sí àpéjọ náà lọ́jọ́ Sunday, ó sì sọ pé: “Inú mi dùn pé ‘Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé’! ni àkòrí àpéjọ tẹ́ ẹ ṣe yìí. Àkòrí yẹn tuni lára gan-an.” Ó wá fi kún un pé: “Ó máa dáa tẹ́ ẹ bá lè ṣe irú àpéjọ yìí láwọn ìlú tó wà ní Amẹ́ríkà àti láwọn ibòmíì kárí ayé.”

 

Àwọn ọmọdé ń kí àwọn àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè míì káàbọ̀ sí Pápákọ̀ Òfúrufú Miami

Àwọn àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè míì àtàwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ń pe àwọn èèyàn sí àpéjọ náà

Lọ́jọ́ Friday, àwọn àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè míì ń gba ẹ̀dà Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lédè Chinese

Àwọn àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè míì ń ṣàkọsílẹ̀ nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ń lọ lọ́wọ́

Mẹ́ta lára àwọn mọ́kànlélọ́gọ́sàn-án (181) tó ṣèrìbọmi

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ń kí àwọn àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè míì, wọ́n sì ń fún ara wọn lẹ́bùn

Lọ́sàn-án Sunday, àwọn míṣọ́nárì àtàwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì nílẹ̀ òkèèrè wà lórí pápá, wọ́n sì ń juwọ́ sáwọn ará

Arákùnrin Lösch ń kí àwọn míṣọ́nárì àtàwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Sunday

Àwọn ọmọdé ń forin dá àwọn àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè míì lára yá níbi ìkórajọ kan nírọ̀lẹ́