AUGUST 29, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! ti Ọdún 2019 (Èdè Sípáníìṣì) Tí A Ṣe Ní Houston Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
Ọjọ́ Tí A Ṣe É: August 23 sí 25, 2019
Ibi Tí A Ti Ṣe É: Pápá Ìṣeré NRG ní Houston, ìpínlẹ̀ Texas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
Èdè: Sípáníìṣì
Àwọn Tó Wá: 56,167
Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 626
Àwọn Tó Wá Láti Ilẹ̀ Òkèèrè: 5,500
Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá A Pè: Ajẹntínà, Bòlífíà, Central America, Chile, Kòlóńbíà, Dominican Republic, Ecuador, Faransé, Ítálì, Japan, Peru, Philippines, Spain, Trinidad and Tobago, Fẹnẹsúélà
Ìrírí: Joelle Hardin tó ń ṣe kòkáárí iléeṣẹ́ Space Center Houston sọ pé: “Láàárọ̀ yìí, ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ mi tó ń yẹ tíkẹ́ẹ̀tì àwọn àlejò wò bí wọn ṣe ń wọlé sínú gbọ̀ngàn wá bá mi, ó sì sọ pé: ‘Joelle, . . . gbogbo àwọn èèyàn yìí ló ń wo ojú mi, lẹ́yìn náà wọ́n á sọ pé, “Ẹ ṣeun,” oríṣiríṣi èdè láwọn míì tiẹ̀ fi ń sọ bẹ́ẹ̀.’ Ìyẹn múnú ẹ̀ dùn gan-an. Mi ò tíì rí i kó láyọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí.”
Àwọn àlejò ń dé sí pápá ìṣeré náà láàárọ̀
Àwọn àlejò tó wá ń wàásù pẹ̀lú àwọn ará tó ń gbé lágbègbè náà
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará ń ṣiṣẹ́ kára kí Pápá Ìṣeré NRG lè wà ní mímọ́ tónítóní kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Friday tó bẹ̀rẹ̀
Méjì nínú àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (626) arákùnrin àti arábìnrin tó ṣèrìbọmi
Arákùnrin Mark Sanderson, tó jẹ́ ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ń sọ àsọyé tó kẹ́yìn ní ọ̀sán Friday
Àwọn àlejò ń ṣe àkọsílẹ̀ bí wọn ṣe ń tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Arábìnrin kan ń mú àwọn àlejò yí ká ibi tí wọ́n kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sáyẹ́ǹsì sí, ìyẹn Houston Museum of Natural Science, tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ibi ìgbafẹ́ tí a ṣètò fún àwọn tó wá
Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń dá àwùjọ lára yá lákòókò àpèjẹ alẹ́
Àwọn tó ń ṣe àkànṣe iṣé ìsìn alákòókò kíkún ń juwọ́ láti orí pápá lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ Sunday