Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 23, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! ti Ọdún 2019 Tí A Ṣe Ní St. Louis Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! ti Ọdún 2019 Tí A Ṣe Ní St. Louis Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
  • Ọjọ́ Tí A Ṣe É: August 16 sí 18, 2019

  • Ibi Tí A Ti Ṣe É: Ilé Olórùlé Rìbìtì tí wọ́n ń pè ní “The Dome” tó wà ní St. Louis, Missouri, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

  • Èdè: Gẹ̀ẹ́sì, Croatian

  • Àwọn Tó Wá: 28,122

  • Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 224

  • Àwọn Tó Wá Láti Ilẹ̀ Òkèèrè: 5,000

  • Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá A Pè: Argentina, Australasia, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Kánádà, Central Europe,, Kòlóńbíà, Croatia, Czech-Slovak, Finland, Faransé, Japan, Philippines, Poland, Portugal, Scandinavia, Serbia, South Africa

  • Ìrírí: Martin Gulley, tó jẹ́ agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ Metrolink sọ pé: “O lè sọ pé o nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan tàbí ohun kan. Àmọ́, ó dìgbà tó o bá fi ìfẹ́ yẹn hàn ká tó mọ̀ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán ni. Bí ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe fi hàn pé lóòótọ́ lẹ nífẹ̀ẹ́. Onírẹ̀lẹ̀ ni yín, ó ṣe tán, ìfẹ́ máa ń jẹ́ kí èèyàn rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ ni, kì í jẹ́ kó gbéra ga. Báàjì tó wà láyà mi ló jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé òṣìṣẹ́ Metrolink ni mi, àmọ́ ìfẹ́ la fi ń dá ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀.”

    Jerry Vallely ni ọ̀gá àgbà tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé-iṣẹ́ Bi-State Development (ìyẹn, àjọ elétò ìrìnnà kan tó ń rí sí ìdàgbàsókè ọrọ̀-ajé ní agbègbè St. Louis). Ó sọ pé: “Ìṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe kọ́ ló jẹ́ bàbàrà fún un yín, ohun tó jẹ yín lógún ni àǹfààní táwọn èèyàn máa rí látinú iṣẹ́ náà, ìyẹn àwọn àlejò tó ń bọ̀, àwọn tí ẹ̀ ń bá ṣiṣẹ́ nínú ìlú, àti àwa òṣìṣẹ́ Metrolink tí a wà níbí. Ẹ̀ n ronú nípa bí inú gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń bá ṣiṣẹ́ ṣe máa dùn, bí gbogbo nǹkan ṣe máa gún régé, tá á sì sunwọ̀n sí i.”

 

Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń dúró de àwọn àlejò tó ń bọ̀ wá sí àpéjọ ní pápákọ̀ òfuurufú St. Louis Lambert International Airport

Àwọn àlejò ń wàásù níbi térò pọ̀ sí pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní St. Louis

Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń tún ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣe àpéjọ náà ṣe kó lè mọ́ tónítóní, kí àpéjọ tó bẹ̀rẹ̀

Mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún méjì àti mẹ́rìnlélógún (224) àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó ṣèrìbọmi

Arákùnrin David Splane, tó jẹ́ ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ń sọ àsọyé tó kẹ́yìn ní ọjọ́ kẹta àpéjọ náà

Àwọn àlejò ń rẹ́rìn-ín bí wọn ṣe ń gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà

Lọ́jọ́ Sunday, àwọn tó ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ń juwọ́ sí àwùjọ láti orí pápá

Àwọn àlejò pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó jẹ́ aráàlú jọ ya fọ́tò

Àwọn àlejò ń gbádùn bí wọ́n ṣe n wo àwọn ẹranko nínú ọgbà ẹranko tó wà ní Saint Louis

Àwọn aṣojú ń wo Bíbélì tí wọn ṣí sí Sáàmù 83:18 tó wà ní ibi ìkówèésí St. Louis Public Library, ẹ̀dà Bíbélì King James Version yìí ṣọ̀wọ́n gan-an torí ó wà lára àwọn ẹ̀dà àkọ́kọ́ tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1611. Torí àwọn àlejò tó wá ni St. Louis Public Library ṣe dìídì ṣí Bíbélì náà sí Sáàmù 83:18

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin ń kọrin níbi ìkórajọ tí wọ́n ṣe nírọ̀lẹ́