Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 20, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwọn Iná Tó Jó ní Ìgbèríko California Ba Agbègbè Náà Jẹ́

Àwọn Iná Tó Jó ní Ìgbèríko California Ba Agbègbè Náà Jẹ́

Ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn iná kan jó ní ìpínlẹ̀ California, ó sì ba agbègbè tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgọ́ta àti méjì kìlómítà jẹ́ níbùú àti lóòró (362 square kilometers).

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Amẹ́ríkà ròyìn pé àwọn ará tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje (1,700) ló ti sá kúrò nílé nítorí àwọn iná tó jó léraléra náà. A ò tíì gbọ́ pé ẹnikẹ́ni fara pa tàbí kú. Ní October 10, 2019, iná tó jó àdúgbò Sandalwood tó wà ní Calimesa ba ilé ọ̀kan lára àwọn arákùnrin wa jẹ́. Bákan náà, èéfín ba àwọn ilé kan jẹ́ díẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tó sá kúrò nílé ló ti pa dà sílé.

Ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó ń gbé láwọn ibi tí iná náà ti jó sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí irú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀, kódà, ó yẹ ká tẹnu mọ́ ọn dáadáa. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn ará wa ti kúrò láwọn ibi tí iná náà ti ń jó, ìyẹn sì jẹ́ kó rọrùn fáwọn panápaná láti gbájú mọ́ bí wọ́n ṣe máa pa iná náà dípò kí wọ́n máa wá àwọn èèyàn kiri.”

Àwọn alábòójútó àyíká àti àwọn alàgbà tó ń gbé lágbègbè náà ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti pèsè ìrànwọ́ fún àwọn tó sá kúrò nílé. Ìfẹ́ àti ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí àwọn akéde tó ń gbé lágbègbè yìí fi hàn bùáyà. Torí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ táwọn ará fi hàn, alábòójútó àyíká kan sọ pé: “Kò ṣòro fún wa rárá láti rí ilé táwọn tó sá kúrò nílé máa gbé.”

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí àwọn tó “ti di orísun ìtùnú” fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí iná yìí lé kúrò nílé.—Kólósè 4:11.